4 O si ṣe, nigbati Solomoni di arugbo, awọn obinrin rẹ̀ yi i li ọkàn pada si ọlọrun miran: ọkàn rẹ̀ kò si ṣe dede pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn Dafidi, baba rẹ̀.
5 Nitori Solomoni tọ Aṣtoreti lẹhin, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Milkomu, irira awọn ọmọ Ammoni.
6 Solomoni si ṣe buburu niwaju Oluwa, kò si tọ̀ Oluwa lẹhin ni pipé gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.
7 Nigbana ni Solomoni kọ́ ibi giga kan fun Kemoṣi, irira Moabu, lori oke ti mbẹ niwaju Jerusalemu, ati fun Moleki, irira awọn ọmọ Ammoni.
8 Bẹ̃li o si ṣe fun gbogbo awọn ajeji obinrin rẹ̀, awọn ti nsun turari, ti nwọn si nrubọ fun oriṣa wọn.
9 Oluwa si binu si Solomoni, nitori ọkàn rẹ̀ yipada kuro lọdọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ara hàn a lẹrinmeji.
10 Ti o si paṣẹ fun u nitori nkan yi pe, Ki o má ṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin: ṣugbọn kò pa eyiti Oluwa fi aṣẹ fun u mọ́.