9 Oluwa si binu si Solomoni, nitori ọkàn rẹ̀ yipada kuro lọdọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ara hàn a lẹrinmeji.
10 Ti o si paṣẹ fun u nitori nkan yi pe, Ki o má ṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin: ṣugbọn kò pa eyiti Oluwa fi aṣẹ fun u mọ́.
11 Nitorina Oluwa wi fun Solomoni pe, Nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si pa majẹmu mi, ati aṣẹ mi mọ́, ti mo ti pa laṣẹ fun ọ, ni yiya emi o fà ijọba rẹ ya kuro lọwọ rẹ, emi o si fi i fun iranṣẹ rẹ.
12 Ṣugbọn emi ki yio ṣe e li ọjọ rẹ, nitori Dafidi baba rẹ; emi o fà a ya kuro lọwọ ọmọ rẹ.
13 Kiki pe emi kì yio fà gbogbo ijọba na ya; emi o fi ẹyà kan fun ọmọ rẹ, nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu ti mo ti yàn.
14 Oluwa si gbe ọta kan dide si Solomoni, Hadadi, ara Edomu: iru-ọmọ ọba li on iṣe ni Edomu.
15 O si ṣe, nigbati Dafidi wà ni Edomu, ati ti Joabu olori-ogun goke lọ lati sìn awọn ti a pa, nigbati o pa gbogbo ọkunrin ni Edomu.