21 Nigbati Rehoboamu si wá si Jerusalemu, o ko gbogbo ile Juda jọ, pẹlu ẹya Benjamini, ọkẹ mẹsan enia ti a yàn, ti nwọn iṣe ologun, lati ba ile Israeli ja, lati mu ijọba na pada bọ̀ sọdọ Rehoboamu, ọmọ Solomoni.
22 Ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun tọ̀ Ṣemaiah, enia Ọlọrun wá wipe,
23 Sọ fun Rehoboamu, ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati fun gbogbo ile Juda ati Benjamini, ati fun iyokù awọn enia wipe,
24 Bayi li Oluwa wi, Ẹnyin kò gbọdọ goke bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ba awọn arakunrin nyin jà: ẹ pada olukuluku si ile rẹ̀; nitori nkan yi ati ọdọ mi wá ni. Nwọn si gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, nwọn si pada lati lọ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.
25 Nigbana ni Jeroboamu kọ́ Ṣekemu li oke Efraimu o si ngbe inu rẹ̀; o si jade lati ibẹ lọ, o si kọ́ Penueli.
26 Jeroboamu si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Nisisiyi ni ijọba na yio pada si ile Dafidi:
27 Bi awọn enia wọnyi ba ngoke lọ lati ṣe irubọ ni ile Oluwa ni Jerusalemu, nigbana li ọkàn awọn enia yi yio tun yipada sọdọ oluwa wọn, ani sọdọ Rehoboamu, ọba Juda, nwọn o si pa mi, nwọn o si tun pada tọ̀ Rehoboamu, ọba Juda lọ.