7 Ọba si wi fun enia Ọlọrun na pe, Wá ba mi lọ ile, ki o si tù ara rẹ lara, emi o si ta ọ li ọrẹ.
8 Enia Ọlọrun na si wi fun ọba pe, Bi iwọ o ba fun mi ni idaji ile rẹ, emi kì yio ba ọ lọ ile, emi kì yio si jẹ onjẹ, bẹ̃ni emi kì yio si mu omi nihin yi.
9 Nitori bẹ̃ li a pa a laṣẹ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Máṣe jẹ onjẹ, má si ṣe mu omi, bẹ̃ni ki o má si ṣe pada li ọ̀na kanna ti o ba wá.
10 Bẹ̃ li o si ba ọ̀na miran lọ, kò si pada li ọ̀na na ti o gbà wá si Beteli.
11 Woli àgba kan si ngbe Beteli: ọmọ rẹ̀ de, o si rohin gbogbo iṣẹ ti enia Ọlọrun na ti ṣe li ọjọ na ni Beteli fun u: ọ̀rọ ti o sọ fun ọba nwọn si sọ fun baba wọn.
12 Baba wọn si wi fun wọn pe, Ọna wo li o gbà? Nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti ri ọ̀na ti enia Ọlọrun na gbà, ti o ti Juda wá.
13 O si wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun mi. Nwọn si di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun u o si gùn u.