1 O si ṣe, ọ̀rọ Oluwa tọ Jehu, ọmọ Hanani wá, si Baaṣa wipe,
2 Bi o ti ṣepe mo gbé ọ ga lati inu ẽkuru wá, ti mo si ṣe ọ li olori Israeli, enia mi; iwọ si rìn li ọ̀na Jeroboamu, iwọ si ti mu ki Israeli enia mi ki o ṣẹ̀, lati fi ẹ̀ṣẹ wọn mu mi binu;
3 Kiyesi i, emi o mu iran Baaṣa, ati iran ile rẹ̀ kuro; emi o si ṣe ile rẹ̀ bi ile Jeroboamu, ọmọ Nebati.
4 Ẹni Baaṣa ti o ba kú ni ilu li awọn ajá yio jẹ; ati ẹni rẹ̀ ti o kú ni oko li ẹiyẹ oju-ọrun o jẹ.
5 Ati iyokù iṣe Baaṣa, ati ohun ti o ṣe, ati agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
6 Baaṣa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Tirsa: Ela, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
7 Ati pẹlu nipa ọwọ́ Jehu woli, ọmọ Hanani, li ọ̀rọ Oluwa de si Baaṣa, ati si ile rẹ̀, ani nitori gbogbo ibi ti o ṣe niwaju Oluwa, ni fifi iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ mu u binu, ati wiwà bi ile Jeroboamu, ati nitori ti o pa a.