6 Baaṣa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Tirsa: Ela, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
7 Ati pẹlu nipa ọwọ́ Jehu woli, ọmọ Hanani, li ọ̀rọ Oluwa de si Baaṣa, ati si ile rẹ̀, ani nitori gbogbo ibi ti o ṣe niwaju Oluwa, ni fifi iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ mu u binu, ati wiwà bi ile Jeroboamu, ati nitori ti o pa a.
8 Li ọdun kẹrindilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Ela, ọmọ Baaṣa, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Tirsa li ọdun meji.
9 Ati iranṣẹ rẹ̀ Simri, olori idaji kẹkẹ́ rẹ̀, dìtẹ rẹ̀, nigbati o ti wà ni Tirsa, o si mu amupara ni ile Arsa, iriju ile rẹ̀ ni Tirsa.
10 Simri si wọle o si kọlù u, o si pa a, li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, o si jọba ni ipò rẹ̀.
11 O si ṣe, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, bi o ti joko li ori itẹ rẹ̀, o lù gbogbo ile Baaṣa pa: kò kù ọmọde ọkunrin kan silẹ, ati awọn ibatan rẹ̀ ati awọn ọrẹ́ rẹ̀.
12 Bayi ni Simri pa gbogbo ile Baaṣa run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ si Baaṣa nipa ọwọ́ Jehu woli,