19 On si wi fun u pe, Gbé ọmọ rẹ fun mi. Elijah si yọ ọ jade li aiya rẹ̀, o si gbé e lọ si iyara-òke ile nibiti on ngbe, o si tẹ́ ẹ si ori akete tirẹ̀.
20 O si kepe OLUWA, o si wipe, OLUWA Ọlọrun mi, iwọ ha mu ibi wá ba opó na pẹlu lọdọ ẹniti emi nṣe atipo, ni pipa ọmọ rẹ̀?
21 On si nà ara rẹ̀ lori ọmọde na li ẹrinmẹta, o si kepe Oluwa, o si wipe, Oluwa Ọlọrun mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ẹmi ọmọde yi ki o tun padà wá sinu rẹ̀.
22 Oluwa si gbọ́ ohùn Elijah; ẹmi ọmọde na si tun padà wá sinu rẹ̀, o si sọji.
23 Elijah si mu ọmọde na, o si mu u sọkalẹ lati inu iyara-òke na wá sinu ile, o si fi i le iya rẹ̀ lọwọ: Elijah si wipe, Wò o, ọmọ rẹ yè.
24 Obinrin na si wi fun Elijah pe, nisisiyi nipa eyi li emi mọ̀ pe, enia Ọlọrun ni iwọ iṣe, ati pe, ọ̀rọ Oluwa li ẹnu rẹ, otitọ ni.