3 Kuro nihin, ki o si kọju siha ila-õrun, ki o si fi ara rẹ pamọ nibi odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani.
4 Yio si ṣe, iwọ o mu ninu odò na; mo si ti paṣẹ fun awọn ẹiyẹ iwò lati ma bọ́ ọ nibẹ.
5 O si lọ, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa: o si lọ, o si ngbe ẹ̀ba odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani.
6 Awọn ẹiyẹ iwò si mu akara pẹlu ẹran fun u wá li owurọ, ati akara ati ẹran li alẹ: on si mu ninu odò na.
7 O si ṣe lẹhin ọjọ wọnni, odò na si gbẹ, nitoriti kò si òjo ni ilẹ na.
8 Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá wipe,
9 Dide, lọ si Sarefati ti Sidoni, ki o si ma gbe ibẹ: kiyesi i, emi ti paṣẹ fun obinrin opó kan nibẹ lati ma bọ́ ọ.