15 On si wipe, Iwọ mọ̀ pe, ijọba na ti emi ni ri, ati pe, gbogbo Israeli li o fi oju wọn si mi lara pe, emi ni o jọba: ṣugbọn ijọba na si yí, o si di ti arakunrin mi; nitori tirẹ̀ ni lati ọwọ́ Oluwa wá.
16 Nisisiyi, ibere kan ni mo wá bere lọwọ rẹ, máṣe dù mi: O si wi fun u pe, Mã wi.
17 O si wi pe, Mo bẹ ọ, sọ fun Solomoni ọba (nitori kì yio dù ọ,) ki o fun mi ni Abiṣagi, ara Ṣunemu li aya.
18 Batṣeba si wipe, o dara; emi o ba ọba sọrọ nitori rẹ.
19 Batṣeba si tọ Solomoni ọba lọ, lati sọ fun u nitori Adonijah. Ọba si dide lati pade rẹ̀, o si tẹ ara rẹ̀ ba fun u, o si joko lori itẹ́ rẹ̀ o si tẹ́ itẹ fun iya ọba, on si joko lọwọ ọtun rẹ̀.
20 On si wipe, Ibere kekere kan li emi ni ibere lọwọ rẹ; máṣe dù mi. On si wipe, mã tọrọ, iya mi; nitoriti emi kì yio dù ọ.
21 On si wipe, jẹ ki a fi Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, arakunrin rẹ, li aya.