20 On si wipe, Ibere kekere kan li emi ni ibere lọwọ rẹ; máṣe dù mi. On si wipe, mã tọrọ, iya mi; nitoriti emi kì yio dù ọ.
21 On si wipe, jẹ ki a fi Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, arakunrin rẹ, li aya.
22 Solomoni ọba si dahùn, o si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbere Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, kuku bere ijọba fun u pẹlu; nitori ẹgbọ́n mi ni iṣe; fun on pãpa, ati fun Abiatari, alufa, ati fun Joabu, ọmọ Seruiah.
23 Solomoni, ọba si fi Oluwa bura pe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati jubẹ pẹlu, nitori Adonijah sọ̀rọ yi si ẹmi ara rẹ̀.
24 Ati nisisiyi bi Oluwa ti wà, ti o ti fi idi mi mulẹ̀, ti o si mu mi joko lori itẹ́ baba mi, ti o si ti kọ́ ile fun mi, gẹgẹ bi o ti wi, loni ni a o pa Adonijah.
25 Solomoni, ọba si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, o si kọlu u, o si kú.
26 Ati fun Abiatari, alufa, ọba wipe, Lọ si Anatoti, si oko rẹ; nitori iwọ yẹ si ikú: ṣugbọn loni emi kì yio pa ọ, nitori iwọ li o ti ngbe apoti Oluwa Ọlọrun niwaju Dafidi baba mi, ati nitori iwọ ti jẹ ninu gbogbo iyà ti baba mi ti jẹ.