43 Ẽ si ti ṣe ti iwọ kò pa ibura Oluwa mọ, ati aṣẹ ti mo pa fun ọ?
44 Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ mọ̀ gbogbo buburu ti ọkàn rẹ njẹ ọ lẹri, ti iwọ ti ṣe si Dafidi, baba mi: Oluwa yio si yi buburu rẹ si ori ara rẹ.
45 A o si bukun Solomoni ọba, a o si fi idi itẹ́ Dafidi mulẹ niwaju Oluwa lailai.
46 Ọba si paṣẹ fun Benaiah ọmọ Jehoiada, o si jade lọ, o si kọlù u, o si kú. A si fi idi ijọba mulẹ li ọwọ́ Solomoni.