1 BENHADADI, oba Siria si gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ: ọba mejilelọgbọn si mbẹ pẹlu rẹ̀ ati ẹṣin ati kẹkẹ́: o si gokè lọ, o si dóti Samaria, o ba a jagun.
2 O si rán awọn onṣẹ sinu ilu, sọdọ Ahabu, ọba Ìsraeli, o si wi fun u pe, Bayi ni Benhadadi wi.
3 Fadaka rẹ ati wura rẹ ti emi ni; awọn aya rẹ pẹlu ati awọn ọmọ rẹ, ani awọn ti o dara jùlọ, temi ni nwọn.
4 Ọba Israeli si dahùn o si wipe, oluwa mi, ọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ tirẹ li emi, ati ohun gbogbo ti mo ni.
5 Awọn onṣẹ si tun padà wá, nwọn si wipe, Bayi ni Benhadadi sọ wipe, Mo tilẹ ranṣẹ si ọ wipe, Ki iwọ ki o fi fadaka rẹ ati wura rẹ, ati awọn aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ le mi lọwọ;
6 Nigbati emi ba rán awọn iranṣẹ mi si ọ ni iwòyi ọla, nigbana ni nwọn o wá ile rẹ wò, ati ile awọn iranṣẹ rẹ; yio si ṣe, ohunkohun ti o ba dara loju rẹ, on ni nwọn o fi si ọwọ́ wọn, nwọn o si mu u lọ.