16 Nwọn si jade lọ li ọjọ-kanri. Ṣugbọn Benhadadi mu amupara ninu agọ, on, ati awọn ọba, awọn ọba mejilelọgbọn ti nràn a lọwọ.
17 Awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko tètekọ jade lọ: Benhadadi si ranṣẹ jade, nwọn si sọ fun u wipe, awọn ọkunrin nti Samaria jade wá.
18 On si wipe, Bi nwọn ba bá ti alafia jade, ẹ mu wọn lãye; tabi bi ti ogun ni nwọn ba bá jade, ẹ mu wọn lãye.
19 Bẹ̃ni awọn ipẹrẹ̀ wọnyi ti awọn ijoye igberiko jade ti ilu wá, ati ogun ti o tẹle wọn.
20 Nwọn si pa, olukuluku ọkunrin kọkan; awọn ara Siria sa; Israeli si lepa wọn: Benhadadi, ọba Siria si sala lori ẹṣin pẹlu awọn ẹlẹṣin.
21 Ọba Israeli si jade lọ, o si kọlu awọn ẹṣin ati kẹkẹ́, o pa awọn ara Siria li ọ̀pọlọpọ.
22 Woli na si wá sọdọ ọba Israeli, o si wi fun u pe, Lọ, mu ara rẹ giri, ki o si mọ̀, ki o si wò ohun ti iwọ nṣe: nitori li amọdun, ọba Siria yio goke tọ̀ ọ wá.