1 ỌDUN mẹta si rekọja laisi ogun lãrin Siria ati lãrin Israeli.
2 O si ṣe li ọdun kẹta, Jehoṣafati, ọba Juda sọkalẹ tọ ọba Israeli wá.
3 Ọba Israeli si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹnyin ha mọ̀ pe, tiwa ni Ramoti-Gileadi, awa si dakẹ, a kò si gbà a kuro lọwọ ọba Siria?
4 O si wi fun Jehoṣafati pe, Iwọ o ha bá mi lọ si ogun Ramoti-Gileadi bi? Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.
5 Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Mo bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa li oni yi.
6 Nigbana ni ọba Israeli kó awọn woli jọ, bi irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki emi ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Goke lọ: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.
7 Jehoṣafati si wipe, Kò si woli Oluwa kan nihin pẹlu, ti awa iba bère lọwọ rẹ̀?