2 Kiki pe, awọn enia nrubọ ni ibi giga, nitori a kò ti ikọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, titi di ọjọ wọnnì.
3 Solomoni si fẹ Oluwa, o si nrin nipa aṣẹ Dafidi baba rẹ̀: ṣugbọn kiki pe, o nrubọ, o si nfi turari jona ni ibi-giga.
4 Ọba si lọ si Gibeoni lati rubọ nibẹ; nitori ibẹ ni ibi-giga nlanla: ẹgbẹrun ọrẹ ẹbọ-sisun ni Solomoni ru lori pẹpẹ na.
5 Ni Gibeoni ni Oluwa fi ara rẹ̀ hàn Solomoni loju alá li oru: Ọlọrun si wipe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ.
6 Solomoni si wipe, Iwọ ti ṣe ore nla fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi, gẹgẹ bi o ti rin niwaju rẹ li otitọ ati li ododo, ati ni iduro-ṣinṣin ọkàn pẹlu rẹ, iwọ si pa ore nla yi mọ fun u lati fun u li ọmọkunrin ti o joko lori itẹ rẹ̀, gẹgẹ bi o ti ri loni yi.
7 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun mi, iwọ ti fi iranṣẹ rẹ jẹ ọba ni ipo Dafidi, baba mi: ati emi, ọmọ kekere ni mi, emi kò si mọ̀ jijade ati wiwọle.
8 Iranṣẹ rẹ si mbẹ lãrin awọn enia rẹ ti iwọ ti yàn, enia pupọ, ti a kò le moye, ti a kò si lè kà fun ọ̀pọlọpọ.