11 Solomoni si fun Hiramu ni ẹgbãwa oṣuwọ̀n ọkà ni onjẹ fun ile rẹ̀, ati ogún oṣuwọ̀n ororo daradara; bẹ̃ni Solomoni nfi fun Hiramu li ọdọdun.
12 Oluwa si fun Solomoni li ọgbọ́n gẹgẹ bi o ti wi fun u: alafia si wà lãrin Hiramu ati Solomoni; awọn mejeji si ṣe adehùn.
13 Solomoni ọba, si ṣà asìnrú enia jọ ni gbogbo Israeli; awọn asìnrú na jẹ ẹgbã mẹdogun enia.
14 O si ràn wọn lọ si Lebanoni, ẹgbarun loṣoṣu, li ọwọ̀-ọwọ́; nwọn wà ni Lebanoni loṣu kan, nwọn a si gbe ile li oṣu meji: Adoniramu li o si ṣe olori awọn alasìnru na.
15 Solomoni si ni ẹgbã marundilogoji enia ti nru ẹrù, ọkẹ mẹrin gbẹnagbẹna lori oke;
16 Laikà awọn ijoye ninu awọn ti a fi ṣe olori iṣẹ Solomoni, ẹgbẹrindilogun o le ọgọrun enia, ti o nṣe alaṣẹ awọn enia ti nṣisẹ na.
17 Ọba si paṣẹ, nwọn si mu okuta wá, okuta iyebiye, ati okuta gbígbẹ lati fi ipilẹ ile na le ilẹ.