14 O si ràn wọn lọ si Lebanoni, ẹgbarun loṣoṣu, li ọwọ̀-ọwọ́; nwọn wà ni Lebanoni loṣu kan, nwọn a si gbe ile li oṣu meji: Adoniramu li o si ṣe olori awọn alasìnru na.
15 Solomoni si ni ẹgbã marundilogoji enia ti nru ẹrù, ọkẹ mẹrin gbẹnagbẹna lori oke;
16 Laikà awọn ijoye ninu awọn ti a fi ṣe olori iṣẹ Solomoni, ẹgbẹrindilogun o le ọgọrun enia, ti o nṣe alaṣẹ awọn enia ti nṣisẹ na.
17 Ọba si paṣẹ, nwọn si mu okuta wá, okuta iyebiye, ati okuta gbígbẹ lati fi ipilẹ ile na le ilẹ.
18 Awọn akọle Solomoni, ati awọn akọle Hiramu si gbẹ́ wọn, ati awọn ara Gebali: nwọn si pèse igi ati okuta lati kọ́ ile na.