7 O si ṣe, nigbati Hiramu gbọ́ ọ̀rọ Solomoni, o yọ̀ pipọ, o si wipe, Olubukún li Oluwa loni, ti o fun Dafidi ni ọmọ ọlọgbọ́n lori awọn enia pupọ yi.
8 Hiramu si ranṣẹ si Solomoni pe, Emi ti gbọ́ eyi ti iwọ ránṣẹ si mi, emi o ṣe gbogbo ifẹ rẹ niti igi kedari ati niti igi firi.
9 Awọn ọmọ ọdọ mi yio mu igi na sọkalẹ lati Lebanoni wá si okun: emi o si fi wọn ṣọwọ si ọ ni fifó li omi okun titi de ibi ti iwọ o nà ika si fun mi, emi o si mu ki nwọn ki o ko wọn sibẹ, iwọ o si ko wọn lọ: iwọ o si ṣe ifẹ mi, lati fi onjẹ fun ile mi.
10 Bẹ̃ni Hiramu fun Solomoni ni igi kedari ati igi firi gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀.
11 Solomoni si fun Hiramu ni ẹgbãwa oṣuwọ̀n ọkà ni onjẹ fun ile rẹ̀, ati ogún oṣuwọ̀n ororo daradara; bẹ̃ni Solomoni nfi fun Hiramu li ọdọdun.
12 Oluwa si fun Solomoni li ọgbọ́n gẹgẹ bi o ti wi fun u: alafia si wà lãrin Hiramu ati Solomoni; awọn mejeji si ṣe adehùn.
13 Solomoni ọba, si ṣà asìnrú enia jọ ni gbogbo Israeli; awọn asìnrú na jẹ ẹgbã mẹdogun enia.