1. Sam 12 YCE

Ọ̀rọ̀ ìdágbére Samuẹli

1 SAMUELI wi fun gbogbo Israeli pe, Kiye si i, emi ti gbọ́ ohùn nyin, ninu gbogbo eyi ti ẹnyin wi fun mi, emi si ti fi ẹnikan jọba lori nyin.

2 Si wõ, nisisiyi, ọba na nrìn niwaju nyin: emi si ti di arugbo, mo si hewu; si wõ, awọn ọmọ mi si mbẹ lọdọ nyin: emi ti nrìn niwaju nyìn lati igba ewe mi wá titi o fi di oni yi.

3 Wõ, emi nĩ, jẹri si mi niwaju Oluwa, ati niwaju ẹni ami-ororo rẹ̀: malu tani mo gbà ri? tabi kẹtẹkẹtẹ tani mo gbà ri? tani mo rẹjẹ ri? tani mo jẹ ni ìya ri? tabi lọwọ́ tali emi gbà owo abẹtẹlẹ kan ri lati fi bo ara mi loju? emi o si sãn pada fun nyin.

4 Nwọn si wipe, Iwọ kò rẹ́ wa jẹ ri, bẹ̃ni iwọ kò jẹ ni ni ìya ri, bẹ̃ni iwọ ko gbà nkan lọwọ́ ẹnikẹni wa ri.

5 O si wi fun wọn pe, Oluwa li ẹlẹri si nyin, ati ẹni ami-ororo rẹ̀ ni ẹlẹri loni pe, ẹnyin kò rí nkan lọwọ́ mi. Nwọn si dahùn wipe, On li ẹlẹri.

6 Samueli si wi fun awọn enia na pe, Oluwa li ẹniti o ti yan Mose ati Aaroni, on li ẹni ti o si mu awọn baba nyin goke ti ilẹ Egipti wá.

7 Njẹ nisisiyi ẹ duro jẹ, ki emi ki o le ba nyin sọ̀rọ niwaju Oluwa niti gbogbo iṣẹ ododo Oluwa, eyi ti on ti ṣe fun nyin ati fun awọn baba nyin.

8 Nigbati Jakobu wá si Egipti, ti awọn baba kigbe pe Oluwa, Oluwa si rán Mose ati Aaroni, awọn ẹniti o mu awọn baba nyin ti ilẹ Egypti jade wá, o si mu wọn joko nihinyi.

9 Nwọn si gbagbe Oluwa Ọlọrun wọn, o si tà wọn si ọwọ́ Sisera, olori ogun Hasori, ati si ọwọ́ awọn Filistini, ati si ọwọ́ ọba Moabu, nwọn si ba wọn jà.

10 Nwọn si kigbe pe Oluwa, nwọn si wipe, Awa ti dẹsẹ̀, nitoripe awa ti kọ̀ Oluwa silẹ, awa si ti nsin Baalimu ati Aṣtaroti: ṣugbọn nisisiyi, gba wa lọwọ́ awọn ọta wa, awa o si sìn ọ.

11 Oluwa si ran Jerubbaali, ati Bedani, ati Jefta ati Samueli, nwọn si gbà nyin lọwọ́ awọn ọta nyin niha gbogbo, ẹnyin si joko li alafia.

12 Nigbati ẹnyin si ri pe Nahaṣi ọba awọn ọmọ Ammoni tọ̀ nyin wá, ẹnyin wi fun mi pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ọba yio jẹ lori wa: nigbati Oluwa Ọlọrun nyin jẹ ọba nyin.

13 Njẹ nisisiyi wo ọba na ti ẹnyin yàn, ati ti ẹnyin fẹ, kiye si i, Oluwa fi ọba jẹ fun nyin.

14 Bi ẹnyin ba bẹ̀ru Oluwa, ti ẹnyin si sin i, ti ẹnyin si gbọ́ ohùn rẹ̀, ti ẹnyin ko si tapa si ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ati ọba nyin ti o jẹ lori nyin yio ma wà lẹhin Oluwa Ọlọrun nyin.

15 Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba gbà ohun Oluwa gbọ́, ti ẹ ba si tàpá si ọ̀rọ Oluwa, ọwọ́ Oluwa yio wà lara nyin si ibi, bi o ti wà lara baba nyin.

16 Nitorina nisisiyi ẹ duro ki ẹ si wo nkan nla yi, ti Oluwa yio ṣe li oju nyin.

17 Oni ki ọjọ ikore ọka bi? emi o kepe Oluwa, yio si ran ãra ati ojò; ẹnyin o si mọ̀, ẹnyin o si ri pe iwabuburu nyin pọ̀, ti ẹnyin ṣe li oju Oluwa ni bibere ọba fun ara nyin.

18 Samueli si kepe Oluwa, Oluwa si ran ãra ati ojò ni ọjọ na: gbogbo enia si bẹru Oluwa pupọ ati Samueli.

19 Gbogbo enia si wi fun Samueli pe, Gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ fun awọn iranṣẹ rẹ, ki awa ki o má ba kú: nitori ti awa ti fi buburu yi kun gbogbo ẹṣẹ wa ni bibere ọba fun ara wa.

20 Samueli si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹnyin ti ṣe gbogbo buburu yi: sibẹ ẹ má pada lẹhin Oluwa, ẹ ma fi gbogbo ọkàn nyin sin Oluwa.

21 Ẹ máṣe yipada; nitori yio jasi itẹle ohun asan lẹhin, eyi ti kì yio ni ere; bẹ̃ni kì yio si gbanila; nitori asan ni nwọn.

22 Nitoriti Oluwa kì yio kọ̀ awọn enia rẹ̀ silẹ nitori orukọ rẹ̀ nla: nitoripe o wu Oluwa lati fi nyin ṣe enia rẹ̀.

23 Pẹlupẹlu bi o ṣe ti emi ni, ki a má ri i pe emi si dẹṣẹ̀ si Oluwa ni didẹkun gbadura fun nyin: emi o si kọ́ nyin li ọ̀na rere ati titọ.

24 Ṣugbọn ẹ bẹ̀ru Oluwa, ki ẹ si fi gbogbo ọkàn nyin sin i lododo: njẹ, ẹ ronu ohun nlanla ti o ṣe fun nyin.

25 Ṣugbọn bi ẹnyin ba hu ìwa buburu sibẹ, ẹnyin o ṣegbé t'ẹnyin t'ọba nyin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31