1. Sam 19 YCE

Saulu fẹ́ pa Dafidi

1 SAULU si sọ fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o pa Dafidi.

2 Ṣugbọn Jonatani ọmọ Saulu fẹràn Dafidi pupọ: Jonatani si sọ fun Dafidi pe, Saulu baba mi nwá ọ̀na ati pa ọ, njẹ, mo bẹ̀ ọ, kiyesi ara rẹ titi di owurọ, ki o si joko nibi ikọ̀kọ, ki o si sa pamọ.

3 Emi o si jade lọ, emi o si duro ti baba mi li oko na nibiti iwọ gbe wà, emi o si ba baba mi sọ̀rọ nitori rẹ; eyiti emi ba si ri, emi o sọ fun ọ.

4 Jonatani si sọ̀rọ Dafidi ni rere fun Saulu baba rẹ̀, o si wi fun u pe, Ki a máṣe jẹ ki ọba ki o ṣẹ̀ si iranṣẹ rẹ̀, si Dafidi; nitori kò ṣẹ̀ ọ, ati nitoripe iṣẹ rẹ̀ dara gidigidi fun ọ.

5 Nitoriti o mu ẹmi rẹ̀ lọwọ rẹ̀, o si pa Filistini na, Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla fun gbogbo Israeli: iwọ ri i, o si yọ̀: njẹ, nitori kini iwọ o ṣe dẹṣẹ̀ si ẹjẹ alaiṣẹ, ti iwọ o fi pa Dafidi laiṣẹ?

6 Saulu si gbọ́ ohùn Jonatani: Saulu si bura pe, Bi Oluwa ti wà lãye a ki yio pa a.

7 Jonatani si pe Dafidi, Jonatani si ro gbogbo ọràn na fun u. Jonatani si mu Dafidi tọ Saulu wá, on si wà niwaju rẹ̀, bi igbà atijọ.

8 Ogun si tun wà sibẹ, Dafidi si jade lọ, o si ba awọn Filistini jà, o si pa wọn pupọ; nwọn si sa niwaju rẹ̀.

9 Ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa wá si bà le Saulu, o si joko ni ile rẹ̀ ton ti ẹṣín rẹ̀ li lọwọ rẹ̀: Dafidi a si ma fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara duru.

10 Saulu ti nwá ọ̀na lati fi ẹṣín na gún Dafidi mọ ogiri: ṣugbọn on si yẹra kuro niwaju Saulu: o si sọ ẹṣín na wọnu ogiri: Dafidi si sa, o si fi ara pamọ li oru na.

11 Saulu si rán onṣẹ si ile Dafidi, lati ma ṣọ ọ ati lati pa a li owurọ: Mikali aya Dafidi si wi fun u pe, Bi iwọ kò ba gbà ẹmi rẹ là li alẹ yi, li ọla li a o pa ọ.

12 Mikali si sọ Dafidi kalẹ lati oju ferese kan wá; on si lọ, o sa, o si fi ara rẹ̀ pamọ.

13 Mikali si mu ere, o si tẹ́ ẹ sori akete, o si fi timtim onirun ewurẹ sibẹ fun irọri rẹ̀, o si fi aṣọ bò o.

14 Nigbati Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi, on si wi fun wọn pe, Kò sàn.

15 Saulu si tun ran awọn onṣẹ na lọ iwo Dafidi, o wi pe, Gbe e goke tọ̀ mi wá ti-akete ti-akete ki emi ki o pa a.

16 Nigbati awọn onṣẹ na de, sa wõ, ere li o si wà lori akete, ati timtim onirun ewurẹ fun irọri rẹ̀.

17 Saulu si wi fun Mikali pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi tàn mi jẹ bẹ̃, ti iwọ si fi jọwọ ọta mi lọwọ lọ, ti on si bọ? Mikali si da Saulu lohùn pe, On wi fun mi pe, Jẹ ki emi lọ; ẽṣe ti emi o fi pa ọ?

18 Dafidi si sa, o si bọ, o si tọ Samueli wá ni Rama, o si rò fun u gbogbo eyi ti Saulu ṣe si i. On ati Samueli si lọ, nwọn si ngbe Naoti.

19 A si wi fun Saulu pe, Wõ, Dafidi mbẹ ni Naoti ni Rama.

20 Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi: nigbati nwọn ri ẹgbẹ awọn wolĩ ti nsọtẹlẹ, ati Samueli ti o duro bi olori wọn, Ẹmi Ọlọrun si bà le awọn onṣẹ Saulu, awọn na si nsọtẹlẹ.

21 A si ro fun Saulu, o si ran onṣẹ miran, awọn na si nsọtẹlẹ. Saulu si tun ran onṣẹ lẹ̃kẹta, awọn na si nsọtẹlẹ.

22 On na si lọ si Rama, o si de ibi kanga nla kan ti o wà ni Seku: o si bere, o si wipe, Nibo ni Samueli ati Dafidi gbe wà? ẹnikan si wipe, Wõ, nwọn mbẹ ni Naoti ni Rama.

23 On si lọ sibẹ si Naoti ni Rama: Ẹmi Ọlọrun si ba le on na pẹlu, o si nlọ, o si nsọtẹlẹ titi o fi de Naoti ni Rama.

24 On si bọ aṣọ rẹ̀ silẹ, o si sọtẹlẹ pẹlu niwaju Samueli, o si dubulẹ nihoho ni gbogbo ọjọ na, ati ni gbogbo oru na. Nitorina nwọn si wipe, Saulu pẹlu ha wà ninu awọn woli?

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31