1. Sam 30 YCE

Dafidi bá àwọn ará Amaleki jagun

1 O si ṣe, nigbati Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si bọ̀ si Siklagi ni ijọ kẹta, awọn ara Amaleki si ti kọlu iha ariwa, ati Siklagi, nwọn si ti kun u;

2 Nwọn si ko awọn obinrin ti mbẹ ninu rẹ̀ ni igbekun, nwọn kò si pa ẹnikan, ọmọde tabi agbà, ṣugbọn nwọn ko nwọn lọ, nwọn si ba ọ̀na ti nwọn lọ.

3 Dafidi ati awọn ọmọkunrin si wọ ilu, si wõ, a ti kun u; ati obinrin wọn, ati ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn li a kó ni igbèkun lọ.

4 Dafidi ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun titi agbara kò si si fun wọn mọ lati sọkun.

5 A si kó awọn aya Dafidi mejeji nigbèkun lọ, Ahinoamu ara Jesreeli, ati Abigaili aya, Nabali ara Karmeli.

6 Dafidi si banujẹ gidigidi, nitoripe awọn enia na si nsọ̀rọ lati sọ ọ li okuta, nitoriti inu gbogbo awọn enia na si bajẹ, olukuluku ọkunrin nitori ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati nitori ọmọ rẹ̀ obinrin: ṣugbọn Dafidi mu ara rẹ̀ li ọkàn le ninu Oluwa Ọlọrun rẹ̀.

7 Dafidi si wi fun Abiatari alufa, ọmọ Ahimeleki pe, Emi bẹ̀ ọ, mu efodu fun mi wá nihinyi. Abiatari si mu efodu na wá fun Dafidi.

8 Dafidi si bere lọdọ Oluwa wipe, Ki emi ki o lepa ogun yi bi? emi le ba wọn? O si da a lohùn pe, Lepa: nitoripe ni biba iwọ o ba wọn, ni gbigba iwọ o si ri wọn gbà.

9 Bẹni Dafidi ati ẹgbẹta ọmọkunrin ti mbẹ lọdọ rẹ̀ si lọ, nwọn si wá si ibi odo Besori, apakan si duro.

10 Ṣugbọn Dafidi ati irinwo ọmọkunrin lepa wọn: igba enia ti ãrẹ̀ mu, ti nwọn kò le kọja odò Besori si duro lẹhin.

11 Nwọn si ri ara Egipti kan li oko, nwọn si mu u tọ̀ Dafidi wá, nwọn si fun u li onjẹ, o si jẹ; nwọn si fun u li omi mu;

12 Nwọn si bùn u li akara eso ọpọtọ ati ṣiri ajara gbigbẹ meji: nigbati o si jẹ ẹ tan, ẹmi rẹ̀ si sọji: nitoripe ko jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò si mu omi ni ijọ mẹta li ọsan, ati li oru.

13 Dafidi si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ iṣe? ati nibo ni iwọ ti wá? On si wipe, ọmọ ara Egipti li emi iṣe, ọmọ-ọdọ ọkunrin kan ara Amaleki; oluwa mi si fi mi silẹ, nitoripe lati ijọ mẹta li emi ti ṣe aisan.

14 Awa si gbe ogun lọ siha gusu ti ara Keriti, ati si apa ti iṣe ti Juda, ati si iha gusu ti Kelebu; awa si kun Siklagi.

15 Dafidi si bi i lere pe, Iwọ le mu mi sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun yi lọ bi? On si wipe, Fi Ọlọrun bura fun mi, pe, iwọ kì yio pa mi, bẹ̃ni iwọ kì yio si fi mi le oluwa mi lọwọ; emi o si mu ọ sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun na lọ.

16 O si mu u sọkalẹ, si wõ, nwọn si tànka ilẹ, nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn si njo, nitori ikogun pupọ ti nwọn ko lati ilẹ awọn Filistini wá, ati lati ilẹ Juda.

17 Dafidi si pa wọn lati afẹmọjumọ titi o fi di aṣalẹ ijọ keji: kò si si ẹnikan ti o là ninu wọn, bikoṣe irinwo ọmọkunrin ti nwọn gun ibakasiẹ ti nwọn si sa.

18 Dafidi si gba gbogbo nkan ti awọn ara Amaleki ti ko: Dafidi si gbà awọn obinrin rẹ̀ mejeji.

19 Kò si si nkan ti o kù fun wọn, kekere tabi nla, ọmọkunrin tabi ọmọbinrin, tabi ikogun, tabi gbogbo nkan ti nwọn ti ko: Dafidi si gbà gbogbo wọn.

20 Dafidi si ko gbogbo agutan, ati malu, nwọn si dà wọn ṣaju nkan miran ti nwọn gbà, nwọn si wipe, Eyiyi ni ikogun ti Dafidi.

21 Dafidi si ba igba ọkunrin ti o ti rẹ̀ jù ati tọ̀ Dafidi lẹhin, ti on ti fi silẹ li odò Besori: nwọn si lọ ipade Dafidi, ati lati pade awọn enia ti o pẹlu rẹ̀: Dafidi si pade awọn enia na, o si ki wọn.

22 Gbogbo awọn enia buburu ati awọn ọmọ Beliali ninu awọn ti o ba Dafidi lọ si dahun, nwọn si wipe, Bi nwọn kò ti ba wa lọ, a kì yio fi nkan kan fun wọn ninu ikogun ti awa rí gbà bikoṣe obinrin olukuluku wọn, ati ọmọ wọn; ki nwọn ki o si mu wọn, ki nwọn si ma lọ.

23 Dafidi si wipe, Ẹ má ṣe bẹ̃, enyin ará mi: Oluwa li o fi nkan yi fun wa, on li o si pa wa mọ, on li o si fi ẹgbẹ-ogun ti o dide si wa le wa lọwọ.

24 Tani yio gbọ́ ti nyin ninu ọ̀ran yi? ṣugbọn bi ipin ẹniti o sọkalẹ lọ si ìja ti ri, bẹ̃ni ipin ẹniti o duro ti ẹrù; nwọn o si pin i bakanna.

25 Lati ọjọ na lọ, o si pa a li aṣẹ, o si sọ ọ li ofin fun Israeli titi di oni yi.

26 Dafidi si bọ̀ si Siklagi, o si rán ninu ikogun na si awọn agbà Juda, ati si awọn ọrẹ́ rẹ̀, o si wipe, Wõ, eyi li ẹ̀bun fun nyin, lati inu ikogun awọn ọta Oluwa wá.

27 O si rán a si awọn ti o wà ni Beteli ati si awọn ti o wà ni gusu Ramoti, ati si awọn ti o wà ni Jattiri.

28 Ati si awọn ti o wà ni Aroeri, ati si awọn ti o wà ni Sifmoti, ati si awọn ti o wà ni Eṣtemoa.

29 Ati si awọn ti o wà ni Rakali, ati si awọn ti o wà ni ilu awọn Jerameeli, ati si awọn ti o wà ni ilu awọn ara Keni,

30 Ati si awọn ti o wà ni Homa, ati si awọn ti o wà ni Koraṣani, ati si awọn ti o wà ni Ataki.

31 Ati si awọn ti o wà ni Hebroni, ati si gbogbo ilu wọnni ti Dafidi tikararẹ̀ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ima rin kiri.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31