1. Sam 15 YCE

Àwọn Ọmọ Israẹli bá àwọn ará Amaleki Jagun

1 SAMUELI si wi fun Saulu pe, Oluwa rán mi lati fi ami ororo yàn ọ li ọba, lori enia rẹ̀, lori Israeli, nitorina nisisiyi iwọ fetisi ohùn ọ̀rọ Oluwa.

2 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi ranti eyi ti Amaleki ti ṣe si Israeli, bi o ti lumọ dè e li ọ̀na, nigbati on goke ti Egipti jade wá.

3 Lọ nisisiyi ki o si kọlu Amaleki, ki o si pa gbogbo nkan wọn li aparun, má si ṣe da wọn si; ṣugbọn pa ati ọkunrin ati obinrin wọn, ọmọ kekere ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, malu ati agutan, ibakasiẹ ati kẹtẹkẹtẹ.

4 Saulu si ko awọn enia na jọ pọ̀ o si ka iye wọn ni Telaimu, nwọn si jẹ ogun ọkẹ awọn ọkunrin ogun ẹlẹsẹ, pẹlu ẹgbarun awọn ọkunrin Juda.

5 Saulu si wá si ilu-nla kan ti awọn ara Amaleki, o si ba dè wọn li afonifoji kan.

6 Saulu si wi fun awọn Keniti pe, Ẹ lọ, yẹra kuro larin awọn ara Amaleki, ki emi ki o má ba run nyin pẹlu wọn: nitoripe ẹnyin ṣe ore fun gbogbo awọn ọmọ Israeli nigbati nwọn goke ti Egipti wá. Awọn Keniti yẹra kuro larin Amaleki.

7 Saulu si kọlu Amaleki lati Hafila titi iwọ o fi de Ṣuri, ti o wà li apa keji Egipti.

8 O si mu Agagi Ọba Amaleki lãye, o si fi oju ida run gbogbo awọn enia na.

9 Ṣugbọn Saulu ati awọn enia na da Agagi si, ati eyi ti o dara julọ ninu agutan ati ninu malu, ati ohun eyi ti o dara tobẹ̃ ninu wọn, ati ọdọ-agutan abọpa, ati gbogbo nkan ti o dara; nwọn kò si fẹ pa wọn run: ṣugbọn gbogbo nkan ti kò dara ti kò si nilari ni nwọn parun patapata.

Ọlọrun kọ Saulu lọ́ba

10 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Samueli wá wipe,

11 Emi kãnu gidigidi ti emi fi Saulu jọba: nitoriti o ti yipada lẹhin mi, kò si mu ọ̀rọ mi ṣẹ. O si ba Samueli ninu jẹ gidigidi; on si kepe Oluwa ni gbogbo oru na.

12 Nigbati Samueli si dide ni kutukutu owurọ̀ lati pade Saulu, nwọn si sọ fun Samueli pe, Saulu ti wá si Karmeli, sa wõ, on kọ ibi kan fun ara rẹ̀ o si ti lọ, o si kọja siwaju, o si sọkalẹ lọ si Gilgali.

13 Samueli si tọ Saulu wá: Saulu si wi fun u pe, Alabukún ni ọ lati ọdọ Oluwa wá: emi ti ṣe eyi ti Oluwa ran mi.

14 Samueli si wipe, njẹ ewo ni igbe agutan ti emi ngbọ́ li eti mi, ati igbe malu ti emi ngbọ́?

15 Saulu si wi fun u pe, eyi ti nwọn mu ti Amaleki wá ni, ti awọn enia dasi ninu awọn agutan ton ti malu ti o dara julọ lati fi rubọ si Oluwa Ọlọrun rẹ; a si pa eyi ti o kù run.

16 Samueli si wi fun Saulu pe, Duro, emi o si sọ eyi ti Oluwa wi fun mi li alẹ yi. On si wi fun u pe, Ma wi.

17 Samueli si wipe, Iwọ kò ha kere loju ara rẹ nigbati a fi ọ ṣe olori ẹya Israeli, ti Oluwa fi àmi ororo sọ ọ di ọba Israeli?

18 Oluwa si rán ọ ni iṣẹ, o si wipe, Lọ, ki o si pa awọn ẹlẹṣẹ ara Amaleki run, ki o si ba wọn jà titi o fi run wọn.

19 Eha si ti ṣe ti iwọ kò fi gbọ́ ohùn Oluwa ṣugbọn iwọ si sare si ikogun, ti iwọ si ṣe buburu li oju Oluwa.

20 Saulu si wi fun Samueli pe, Nitotọ, emi gbà ohùn Oluwa gbọ́, emi si ti lọ li ọ̀na ti Oluwa ran mi, emi si ti mu Agagi ọba Amaleki wá, emi si ti pa ara Amaleki run.

21 Ṣugbọn awọn enia na ti mu ninu ikogun, agutan ati malu, pàtaki nkan wọnni ti a ba pa run, lati fi rubọ si Oluwa Ọlọrun rẹ ni Gilgali.

22 Samueli si wipe, Oluwa ha ni inu-didun si ọrẹ sisun ati ẹbọ bi pe ki a gbà ohùn Oluwa gbọ́? kiye si i, igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilẹ̀ si sàn jù ọra àgbo lọ.

23 Nitoripe iṣọtẹ dabi ẹ̀ṣẹ afọṣẹ, ati agidi gẹgẹ bi ìwa buburu ati ibọriṣa. Nitoripe iwọ kọ̀ ọ̀rọ Oluwa, on si kọ̀ ọ li ọba.

24 Saulu si wi fun Samueli pe, Emi ti ṣẹ̀: nitoriti emi ti re ofin Oluwa kọja, ati ọ̀rọ rẹ̀: nitori emi bẹ̀ru awọn enia, emi si gbà ohùn wọn gbọ́.

25 Ṣugbọn nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ mi jì mi, ki o sì yipada pẹlu mi, ki emi ki o le tẹriba niwaju Oluwa.

26 Samueli si wi fun Saulu pe, emi kì yio tun yipada pẹlu rẹ mọ nitoriti iwọ ti kọ̀ ọ̀rọ Oluwa, Oluwa si ti kọ̀ iwọ lati ma jẹ ọba lori Israeli.

27 Bi Samueli si ti yipada lati lọ, o si di ẹ̀wu ileke rẹ̀ mu, o si faya mọ̃ lọwọ́.

28 Samueli si wi fun u pe, Oluwa fa ijọba Israeli ya kuro lọwọ rẹ loni, o si fi fun aladugbo rẹ kan, ti o sàn ju ọ lọ.

29 Agbara Israeli kì yio ṣeke bẹ̃ni kì yio si ronupiwada: nitoripe ki iṣe ẹda ti yio fi ronupiwada.

30 O si wipe, emi ti dẹ̀ṣẹ: ṣugbọn bu ọlá fun mi, jọwọ, niwaju awọn agbãgbà enia mi, ati niwaju Israeli, ki o si tun yipada pẹlu mi, ki emi ki o le tẹriba niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ.

31 Samueli si yipada, o si tẹle Saulu; Saulu si tẹriba niwaju Oluwa.

32 Samueli si wipe, Mu Agagi ọba awọn ara Amaleki na tọ̀ mi wá nihinyi. Agagi si tọ̀ ọ wá ni idaraya. Agagi si wipe, Nitotọ ikoro ikú ti kọja.

33 Samueli si wipe, Gẹgẹ bi idà rẹ ti sọ awọn obinrin di alaili ọmọ, bẹ̃ gẹgẹ ni iya rẹ yio si di alaili ọmọ larin obinrin. Samueli si pa Agagi niwaju Oluwa ni Gilgali.

34 Samueli si lọ si Rama; Saulu si goke lọ si ile rẹ̀ ni Gibea ti Saulu.

35 Samueli kò si tun pada wá mọ lati wo Saulu titi o fi di ọjọ ikú rẹ̀: ṣugbọn Samueli kãnu fun Saulu: o si dùn Oluwa nitori on fi Saulu jẹ ọba lori Israeli.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31