1. Sam 4 YCE

Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí lọ́wọ́ àwọn Ọmọ Israẹli

1 Ọ̀RỌ Samueli si wá si gbogbo Israeli: Israeli si jade lọ pade awọn Filistini lati jagun, nwọn do si eti Ebeneseri: awọn Filistini si do ni Afeki.

2 Awọn Filistini si tẹ itẹgun lati pade Israeli: nigbati nwọn pade ija, awọn Filistini si le Israeli: nwọn si pa iwọn ẹgbaji ọkunrin ni itẹgun ni papa.

3 Awọn enia si de budo, awọn agbà Israeli si wipe, Nitori kini Oluwa ṣe le wa loni niwaju awọn Filistini? Ẹ jẹ ki a mu apoti majẹmu Oluwa ti mbẹ ni Ṣilo sọdọ wa, pe, nigbati o ba de arin wa, ki o le gba wa kuro lọwọ awọn ọta wa.

4 Bẹli awọn enia si ranṣẹ si Ṣilo, pe ki nwọn gbe lati ibẹ wá apoti majẹmu Oluwa awọn ọmọ-ogun ẹniti o joko larin awọn kerubu: ati awọn ọmọ Eli mejeji, Hofni ati Finehasi, wà nibẹ pẹlu apoti majẹmu Ọlọrun.

5 Nigbati apoti majẹmu Oluwa de budo, gbogbo Israeli si ho yè, tobẹ̃ ti ilẹ mì.

6 Nigbati awọn Filistini si gbọ́ ohùn ariwo na, nwọn si wipe, Ohùn ariwo nla kili eyi ni budo awọn Heberu? O si wa ye wọn pe, apoti majẹmu Oluwa li o de budo.

7 Ẹ̀ru si ba awọn Filistini, nwọn si wipe, Ọlọrun wọ budo. Nwọn si wipe, Awa gbe! nitoripe iru nkan bayi kò si ri.

8 A gbe! tani yio gbà wa lọwọ Ọlọrun alagbara wọnyi? awọn wọnyi li Ọlọrun ti o fi gbogbo ipọnju pọn Egipti loju li aginju.

9 Ẹ jẹ alagbara, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹnyin Filistini, ki ẹnyin máṣe ẹrú fun awọn Heberu, bi nwọn ti nṣe ẹrú nyin ri: Ẹ ṣe bi ọkunrin, ki ẹ si ja.

10 Awọn Filistini si ja, nwọn si lé Israeli, nwọn si sa olukuluku sinu ago rẹ̀: ipani si pọ̀ gidigidi, awọn ẹlẹsẹ ti o ṣubu ninu ogun Israeli jẹ ẹgbãmẹdogun.

11 Nwọn si gbà apoti ẹri Ọlọrun: ọmọ Eli mejeji si kú, Hofni ati Finehasi.

Ikú Eli

12 Ọkunrin ara Benjamini kan sa lati ogun wá o si wá si Ṣilo lọjọ kanna, ti on ti aṣọ rẹ̀ fifaya, ati erupẹ lori rẹ̀.

13 Nigbati o si de, si wõ, Eli joko lori apoti kan lẹba ọ̀na o nṣọna: nitori aiyà rẹ̀ kò balẹ nitori apoti Ọlọrun. Ọkunrin na si wọ ilu lati rohin, gbogbo ilu fi igbe ta.

14 Eli si gbọ́ ohùn igbe na, o sì wipe, Ohùn igbe kili eyi? ọkunrin na si yara wá o si rò fun Eli.

15 Eli si di ẹni ejidilọgọrun ọdun; oju rẹ̀ di baibai, kò si le riran.

16 Ọkunrin na si wi fun Eli pe, Emi li ẹniti o ti ogun wá, loni ni mo sa ti ogun na wá; o si bi i pe, Eti ri, ọmọ mi?

17 Ẹniti o mu ihin wá si dahun o si wipe, Israeli sa niwaju awọn Filistini, iṣubu na si pọ ninu awọn enia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji, Hofni ati Finehasi si kú, nwọn si gbà apoti Ọlọrun.

18 O sì ṣe, nigbati o darukọ apoti Ọlọrun, o ṣubu ṣehin kuro lori apoti lẹba bode, ọrun rẹ̀ si ṣẹ, o si kú: nitori o di arugbo tan, o si tobi. O si ṣe idajọ Israeli li ogoji ọdun.

Ikú Opó Finehasi

19 Aya ọmọ rẹ̀, obinrin Finehasi, loyun, o si sunmọ ọjọ ibi rẹ̀; nigbati o si gbọ́ ihìn pe a ti gbà apoti Ọlọrun, ati pe, baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ kú, o kunlẹ, o si bimọ, nitori obí tẹ̀ ẹ.

20 Lakoko ikú rẹ̀ awọn obinrin ti o duro tì i si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; nitoriti iwọ bi ọmọkunrin kan. Ko dahun, kò si kà a si.

21 On si pe ọmọ na ni Ikabodu, wipe, Kò si ogo fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun, ati nitori ti baba ọkọ rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀.

22 O si wipe, Ogo kò si fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31