1. Sam 14 YCE

Jonatani hùwà akikanju

1 O si ṣe li ọjọ kan, Jonatani ọmọ Saulu si wi fun ọdọmọkunrin ti o nru ihamọra rẹ̀, pe, Wá, jẹ ki a rekọja lọ si ibudo-ogun awọn Filistini ti o wà niha keji. Ṣugbọn on kò sọ fun baba rẹ̀.

2 Saulu si duro ni iha ipinlẹ Gibea labẹ igi ìbo eyi ti o wà ni Migronu: awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ to iwọn ẹgbẹta ọkunrin.

3 Ahia ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, alufa Oluwa ni Ṣilo, ti nwọ̀ Efodu. Awọn enia na kò si mọ̀ pe Jonatani ti lọ.

4 Larin meji ọ̀na wọnni, eyi ti Jonatani ti nwá lati lọ si ile ọmọ-ogun olodi ti Filistini, okuta mimú kan wà li apa kan, okuta mímú kan si wà li apa keji: orukọ ekini si njẹ Bosesi, orukọ ekeji si njẹ Sene.

5 Ṣonṣo okuta ọkan wà ni ariwa kọju si Mikmaṣi, ti ekeji si wà ni gusù niwaju Gibea.

6 Jonatani wi fun ọdọmọdekunrin ti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Wá, si jẹ ki a lọ si budo-ogun awọn alaikọla yi: bọya Oluwa yio ṣiṣẹ fun wa: nitoripe kò si idiwọ fun Oluwa lati fi pipọ tabi diẹ gba là.

7 Ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ na wi fun u pe, Ṣe gbogbo eyi ti o mbẹ li ọkàn rẹ: ṣe bi o ti tọ́ li ọkàn rẹ; wõ, emi wà pẹlu rẹ gẹgẹ bi ti ọkàn rẹ.

8 Jonatani si wi pe, Kiye si i, awa o rekọja sọdọ awọn ọkunrin wọnyi, a o si fi ara wa hàn fun wọn.

9 Bi nwọn ba wi fun wa pe, Ẹ duro titi awa o fi tọ̀ nyin wá; awa o si duro, awa kì yio si goke tọ̀ wọn lọ.

10 Ṣugbọn bi nwọn ba wi pe, Goke tọ̀ wa wá; a o si goke lọ: nitori pe Oluwa ti fi wọn le wa lọwọ́; eyi ni o si jẹ àmi fun wa.

11 Awọn mejeji fi ara wọn hàn fun ogun Filistini: awọn Filistini si wipe, Wõ, awọn Heberu ti inu iho wọn jade wá, nibiti nwọn ti fi ara pamọ si.

12 Awọn ọkunrin ile olodi na si da Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, Goke tọ̀ wa wá, awa o si fi nkan hàn nyin; Jonatani si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Ma tọ̀ mi lẹhìn; nitoripe Oluwa ti fi wọn le awọn enia Israeli lọwọ.

13 Jonatani rakò goke, ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ lẹhin rẹ̀; awọn Filistini si subu niwaju Jonatani; ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ npa lẹhin rẹ̀.

14 Pipa ikini, eyi ti Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ ṣe, o jasi iwọn ogún ọkunrin ninu abọ iṣẹko kan ti malu meji iba tú.

15 Ibẹ̀ru si wà ninu ogun na, ni pápá, ati ninu gbogbo awọn enia na; ile ọmọ-ogun olodi, ati awọn ti iko ikogun, awọn pẹlu bẹ̀ru; ilẹ sì mi: bẹ̃li o si jasi ọwáriri nlanla.

Àwọn Ọmọ Ogun Israẹli ṣẹgun Àwọn ti Filistini

16 Awọn ọkunrin ti nṣọ́na fun Saulu ni Gibea ti Benjamini wò; nwọn si ri ọpọlọpọ awọn enia na tuka, nwọn si npa ara wọn bi nwọn ti nlọ.

17 Saulu si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ kà awọn enia na ki ẹ si mọ̀ ẹniti o jade kuro ninu wa. Nwọn si kà, si kiye si i, Jonatani ati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ kò si si.

18 Saulu si wi fun Ahia pe, Gbe apoti Ọlọrun na wá nihinyi. Nitoripe apoti Ọlọrun wà lọdọ awọn ọmọ Israeli li akokò na.

19 O si ṣe, bi Saulu ti mba alufa na sọ̀rọ, ariwo ti o wà ni budo awọn Filistini si npọ̀ si i: Saulu si wi fun alufa na pe, dawọ́ duro.

20 Saulu ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀ ko ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá si oju ija: kiye si i, ida olukuluku si wà li ara ọmọnikeji rẹ̀, rudurudu na si pọ̀ gidigidi.

21 Pẹlupẹlu awọn Heberu ti o wà lọdọ awọn Filistini nigba atijọ, ti o si ti goke ba wọn lọ si budo lati ilu ti o wà yikakiri, awọn na pẹlu si yipada lati dapọ̀ mọ awọn Israeli ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani.

22 Bẹ̃ gẹgẹ nigbati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ti o ti pa ara wọn mọ ninu okenla Efraimu gbọ́ pe awọn Filistini sa, awọn na pẹlu tẹle wọn lẹhin kikan ni ijà na.

23 Bẹ̃li Oluwa si gbà Israeli là lọjọ na: ija na si rekọja si Bet-afeni.

Àwọn Ohun tí Ó Ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ogun

24 Awọn ọkunrin Israeli si ri ipọnju gidigidi ni ijọ na: nitoriti Saulu fi awọn enia na bu pe, Ifibu ni fun ẹniti o jẹ onjẹ titi di alẹ titi emi o si fi gbẹsan lara awọn ọta mi. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu awọn enia na ti o fi ẹnu kan onjẹ.

25 Gbogbo awọn ara ilẹ na si de igbo kan, oyin sì wà lori ilẹ na.

26 Nigbati awọn enia si wọ inu igbo na, si kiye si i oyin na nkán; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o mu ọwọ́ rẹ̀ re ẹnu rẹ̀: nitoripe awọn enia bẹ̀ru ifibu na.

27 Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nigbati baba rẹ̀ fi ifibu kilọ fun awọn enia na: o si tẹ ori ọpa ti mbẹ lọwọ rẹ̀ bọ afara oyin na, o si fi i si ẹnu rẹ̀, oju rẹ̀ mejeji si walẹ.

28 Nigbana li ọkan ninu awọn enia na dahùn wipe, baba rẹ ti fi ifibu kilọ fun awọn enia na, pe, ifibu li ọkunrin na ti o jẹ onjẹ li oni. Arẹ̀ si mu awọn enia na.

29 Nigbana ni Jonatani wipe, baba mi yọ ilu li ẹnu, sa wo bi oju mi ti walẹ, nitori ti emi tọ diẹ wò ninu oyin yi.

30 A! nitotọ, ibaṣepe awọn enia na ti jẹ ninu ikogun awọn ọta wọn ti nwọn ri, pipa awọn Filistini iba ti pọ to?

31 Nwọn pa ninu awọn Filistini li ọjọ na, lati Mikmaṣi de Aijaloni: o si rẹ̀ awọn enia na gidigidi.

32 Awọn enia sare si ikogun na, nwọn si mu agutan, ati malu, ati ọmọ-malu, nwọn si pa wọn sori ilẹ: awọn enia na si jẹ wọn t'ẹjẹ t'ẹjẹ.

33 Nigbana ni nwọn wi fun Saulu pe, kiye si i, awọn enia na dẹ̀ṣẹ si Oluwa, li eyi ti nwọn jẹ ẹjẹ. On si wipe, Ẹnyin ṣẹ̀ kọja: yi okuta nla fun mi wá loni.

34 Saulu si wipe, Ẹ tu ara nyin ka sarin awọn enia na ki ẹ si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ọkunrin mu malu tirẹ̀ tọ̀ mi wá, ati olukuluku ọkunrin agutan rẹ̀, ki ẹ si pa wọn nihin, ki ẹ si jẹ, ki ẹ má si ṣẹ̀ si Oluwa, ni jijẹ ẹjẹ. Gbogbo enia olukuluku ọkunrin mu malu rẹ̀ wá li alẹ na, nwọn si pa wọn ni ibẹ̀.

35 Saulu si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa; eyi ni pẹpẹ ti o kọ ṣe fun Oluwa.

36 Saulu wipe, Ẹ jẹ ki a sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ li oru, ki a ba wọn ja titi di imọlẹ owurọ̀, ẹ má jẹ ki a fi ọkunrin kan silẹ ninu wọn. Nwọn si wipe, Ṣe gbogbo eyi ti o tọ loju rẹ. Nigbana ni alufa ni si wipe, Ẹ jẹ ki a sunmọ ihinyi si Ọlọrun.

37 Saulu si bere lọdọ Ọlọrun pe, ki emi ki o sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ bi? Iwọ o fi wọn lé Israeli lọwọ́ bi? ṣugbọn kò da a lohùn li ọjọ na.

38 Saulu si wipe Mu gbogbo awọn àgba enia sunmọ ihinyi, ki ẹ mọ̀, ki ẹ si ri ibiti ẹ̀ṣẹ yi wà loni.

39 Nitoripe gẹgẹ bi Oluwa ti wà ti o ti gbà Israeli là bi o tilẹ ṣepe a ri i lara Jonatani ọmọ mi, nitõtọ yio kú. Ṣugbọn ninu gbogbo enia na, kò si ẹniti o da a lohùn.

40 Saulu si wi fun gbogbo awọn Israeli pe, Ẹnyin lọ si apakan, emi ati Jonatani ọmọ mi a si lọ si apakan. Gbogbo enia si wi fun Saulu pe, Ṣe eyi ti o tọ ni oju rẹ.

41 Saulu si wi fun Oluwa Ọlọrun Israeli pe, fun mi ni ibò ti o pé. A si mu Saulu ati Jonatani: ṣugbọn awọn enia na yege.

42 Saulu si wipe, Di ibò ti emi ati ti Jonatani ọmọ mi. Ibò na si mu Jonatani.

43 Saulu si wi fun Jonatani pe, Sọ nkan ti o ṣe fun mi. Jonatani si sọ fun u, o si wipe, Nitõtọ mo fi ori ọ̀pá ti mbẹ li ọwọ́ mi tọ́ oyin diẹ wò, wõ emi mura ati kú.

44 Saulu si wipe, ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ pẹlu: nitoripe iwọ Jonatani yio sa kú dandan.

45 Awọn enia si wi fun Saulu pe, Jonatani yio kú, ti o ṣe igbala nla yi ni Israeli? ki a má ri i; bi Oluwa ti wà, ọkan ninu irun ori rẹ̀ kì yio bọ́ silẹ; nitoripe o ba Ọlọrun ṣiṣẹ pọ̀ loni. Bẹ̃li awọn enia si gbà Jonatani silẹ, kò si kú.

46 Saulu si ṣiwọ ati ma lepa awọn Filistini: Awọn Filistini si lọ si ilu wọn.

Ìjọba ati Ìdílé Saulu

47 Saulu si jọba lori Israeli; o si bá gbogbo awọn ọta rẹ̀ jà yika, eyini ni Moabu ati awọn ọmọ Ammoni, ati Edomu, ati awọn ọba Soba ati awọn Filistini: ati ibikibi ti o yi si, a bà wọn ninu jẹ.

48 O si ko ogun jọ, o si kọlu awọn Amaleki, o si gbà Israeli silẹ lọwọ awọn ti o nkó wọn.

49 Awọn ọmọ Saulu si ni Jonatani, ati Iṣui, ati Malkiṣua; ati orukọ ọmọbinrin rẹ̀ mejeji si ni wọnyi; orukọ akọbi ni Merabu, ati orukọ aburo ni Mikali:

50 Ati orukọ aya Saulu ni Ahinoamu, ọmọbinrin Ahimaasi, ati orukọ olori ogun rẹ̀ ni Abneri ọmọ Neri arakunrin baba Saulu.

51 Kiṣi si ni baba Saulu; ati Neri ni baba Abneri ọmọ Abieli.

52 Ogun na si le si awọn Filistini ni gbogbo ọjọ Saulu: bi Saulu ba ri ẹnikan ti o li agbara, tabi akikanju ọkunrin, a mu u sọdọ rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31