1. Sam 16 YCE

Wọ́n fi àmì Òróró yan Dafidi lọ́ba

1 OLUWA si wi fun Samueli pe, Yio ti pẹ to ti iwọ o fi ma kãnu Saulu, nigbati o jẹ pe, mo ti kọ̀ ọ lati ma jọba lori Israeli? Fi ororo kún iwo rẹ, ki o si lọ, emi o rán ọ tọ̀ Jesse ara Betlehemu: nitoriti emi ti ri ọba kan fun ara mi ninu awọn ọmọ rẹ̀.

2 Samueli si wi pe, Emi o ti ṣe lọ? bi Saulu ba gbọ́ yio si pa mi. Oluwa si wi fun u pe, mu ọdọ-malu kan li ọwọ́ rẹ, ki o si wipe, Emi wá rubọ si Oluwa.

3 Ki o si pe Jesse si ibi ẹbọ na, emi o si fi ohun ti iwọ o ṣe hàn ọ: iwọ o si ta ororo si ori ẹniti emi o da orukọ fun ọ.

4 Samueli si ṣe eyi ti Oluwa wi fun u, o sì wá si Betlehemu. Awọn agbà ilu na si bẹ̀ru nitori wiwá rẹ̀, nwọn si wipe, Alafia ki iwọ ba wá si bi?

5 On si dahùn wipe, Alafia ni: emi wá rubọ si Oluwa; ẹ ṣe ara nyin ni mimọ́, ki ẹ si wá pẹlu mi si ibi ẹbọ na. On si yà Jesse sí mimọ́, ati awọn ọmọ rẹ̀, o si pe wọn si ẹbọ na.

6 O si ṣe nigbati nwọn de, o ri Eliabu, o si wipe, nitotọ ẹni-àmi-ororo Oluwa mbẹ niwaju rẹ̀.

7 Ṣugbọn Oluwa wi fun Samueli pe, máṣe wo oju rẹ̀, tabi giga rẹ̀; nitoripe emi kọ̀ ọ: nitoriti Oluwa kì iwò bi enia ti nwò; enia a ma wò oju, Oluwa a ma wò ọkàn.

8 Jesse si pe Abinadabu, o si mu ki o kọja niwaju Samueli. On si wipe, Oluwa kò si yan eleyi.

9 Jesse si mu ki Ṣamma ki o kọja. On si wipe, Oluwa kò si yàn eyi.

10 Jesse si tun mu ki awọn ọmọ rẹ̀ mejeje kọja niwaju Samueli. Samueli si wi fun Jesse pe, Oluwa kò yan awọn wọnyi.

11 Samueli si bi Jesse lere pe, gbogbo awọn ọmọ rẹ li o wà nihin bi? On si dahun wipe, abikẹhin wọn li o kù, sa wõ, o nṣọ agutan. Samueli si wi fun Jesse pe, Ranṣẹ ki o si mu u wá: nitoripe awa kì yio joko titi on o fi dé ihinyi.

12 O si ranṣẹ, o si mu u wá. On si jẹ ẹnipupa, ti o lẹwà loju, o si dara lati ma wò. Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si fi ororo sà a li àmi: nitoripe on na li eyi.

13 Nigbana ni Samueli mu iwo ororo, o si fi yà a si ọ̀tọ larin awọn arakunrin rẹ̀; Ẹmi Oluwa si bà le Dafidi lati ọjọ na lọ, Samueli si dide, o si lọ si Rama.

Dafidi ní Ààfin Saulu

14 Ṣugbọn Ẹmi Oluwa fi Saulu silẹ, ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa si nyọ ọ li ẹnu.

15 Awọn iranṣẹ Saulu si wi fun u pe, Jọwọ, sa wõ ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun nyọ ọ li ẹnu.

16 Njẹ ki oluwa wa fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà niwaju rẹ̀ lati wá ọkunrin kan ti o mọ̀ ifi duru kọrin: yio si ṣe nigbati ẹmi buburu na lati ọdọ̀ Ọlọrun wá ba de si ọ, yio si fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara dùru, iwọ o si sàn.

17 Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ ba mi wá ọkunrin kan, ti o mọ̀ iṣẹ́ orin daju, ki ẹ si mu u tọ̀ mi wá.

18 Ọkan ninu iranṣẹ wọnni si dahùn wipe, Wõ emi ri ọmọ Jesse kan ti Betlehemu ti o mọ̀ iṣẹ orin, o si jẹ ẹni ti o li agbara gidigidi, ati ologun, ati ẹni ti o ni ọgbọ́n ọ̀rọ isọ, ati arẹwa, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.

19 Saulu si ran iranṣẹ si Jesse wipe, ran Dafidi ọmọ rẹ si mi, ẹniti o nṣọ agutan.

20 Jesse si mu kẹtẹkẹtẹ, o si di ẹrù akara le e, ati igò ọti-waini, ati ọmọ ewurẹ; o si ran wọn nipa ọwọ Dafidi ọmọ rẹ̀ si Saulu.

21 Dafidi si tọ Saulu lọ, o si duro niwaju rẹ̀: on si fẹ ẹ gidigidi; Dafidi si wa di ẹniti nrù ihamọra rẹ̀.

22 Saulu si ranṣẹ si Jesse pe, Jẹ ki Dafidi, emi bẹ ọ, duro niwaju mi; nitori ti o wù mi.

23 O si ṣe, nigbati ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun wá ba de si Saulu, Dafidi a si fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara duru: a si san fun Saulu, ara rẹ̀ a si da; ẹmi buburu na, a si fi i silẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31