1. Sam 10 YCE

1 SAMUELI si mu igo ororo, o si tu u si i li ori, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si wipe, Kò ṣepe nitoriti Oluwa ti fi ororo yàn ọ li olori ini rẹ̀?

2 Nigbati iwọ ba lọ kuro lọdọ mi loni, iwọ o ri ọkunrin meji li ẹba iboji Rakeli li agbegbe Benjamini, ni Selsa; nwọn o si wi fun ọ pe, Nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ ti iwọ ti jade lọ iwá: si wõ, baba rẹ ti fi ọran ti kẹtẹkẹtẹ silẹ, o si kọ ominu nitori rẹ wipe, Kili emi o ṣe niti ọmọ mi?

3 Iwọ o si kọja lati ibẹ lọ, iwọ o si de pẹtẹlẹ Tabori, nibẹ li ọkunrin mẹta ti nlọ sọdọ Ọlọrun ni Beteli yio pade rẹ, ọkan yio mu, ọmọ ewurẹ mẹta lọwọ, ekeji yio mu iṣù akara mẹta, ati ẹkẹta yio mu igo ọti-waini.

4 Nwọn o si ki ọ, nwọn o si fi iṣù akara meji fun ọ; iwọ o si gbà a lọwọ wọn.

5 Lẹhin eyini iwọ o wá si oke Ọlọrun, nibiti ẹgbẹ ogun awọn Filistini wà; yio si ṣe, nigbati iwọ ba de ilu na, iwọ o si pade ẹgbẹ woli ti yio ma sọkalẹ lati ibi giga nì wá; nwọn o si ni psalteri, ati tabreti, ati fère, ati harpu niwaju wọn, nwọn o si ma sọtẹlẹ.

6 Ẹmi Oluwa yio si bà le ọ, iwọ o si ma ba wọn sọtẹlẹ, iwọ o si di ẹlomiran.

7 Yio si ri bẹ̃, nigbati àmi wọnyi ba de si ọ, ṣe fun ara rẹ ohun gbogbo ti ọwọ́ rẹ ba ri lati ṣe, nitoriti Ọlọrun wà pẹlu rẹ.

8 Iwọ o si ṣaju mi sọkalẹ lọ si Gilgali, si kiye si i, emi o sọkalẹ tọ ọ wá, lati rubọ sisun, ati lati ru ẹbọ irẹpọ̀: ni ijọ meje ni iwọ o duro, titi emi o fi tọ̀ ọ wá, emi o si fi ohun ti iwọ o ṣe han ọ.

9 O si ri bẹ̃ pe, nigbati o yi ẹhin rẹ̀ pada lati lọ kuro lọdọ Samueli, Ọlọrun si fun u li ọkàn miran: gbogbo àmi wọnni si ṣẹ li ọjọ na.

10 Nigbati nwọn si de ibẹ si oke na, si kiye si i, ẹgbẹ awọn woli pade rẹ̀, Ẹmi Ọlọrun si bà le e, on si sọtẹle larin wọn.

11 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ ri pe o nsọtẹlẹ larin awọn woli, awọn enia si nwi fun ara wọn pe, Kili eyi ti o de si ọmọ Kiṣi? Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?

12 Ẹnikan lati ibẹ na wá si dahùn, o si wipe, ṣugbọn tani baba wọn? Bẹ̃li o si wà li owe, Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?

13 Nigbati o sọtẹlẹ tan, o si lọ si ibi giga nì.

14 Arakunrin Saulu kan si wi fun u ati fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Nibo li ẹnyin ti lọ? On si wipe, lati wá awọn kẹtẹkẹtẹ ni: nigbati awa ri pe nwọn kò si nibi kan, awa si tọ Samueli lọ.

15 Arakunrin Saulu na si wipe, Sọ fun mi, emi bẹ̀ ọ, ohun ti Samueli wi fun ọ.

16 Saulu si wi fun arakunrin rẹ̀ pe, On ti sọ fun wa dajudaju pe, nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ nã. Ṣugbọn ọ̀ran ijọba ti Samueli sọ, on kò sọ fun u.

Wọ́n fi ìhó Ayọ̀ gba Saulu ní Ọba

17 Samueli si pe gbogbo enia jọ siwaju Oluwa ni Mispe.

18 O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Emi mu Israeli goke ti Egipti wá, mo si gbà nyin kuro lọwọ́ awọn ara Egipti, ati kuro lọwọ́ gbogbo ijọba wọnni ti o pọn nyin loju.

19 Ẹnyin si kọ̀ Ọlọrun nyin loni, ẹniti on tikara rẹ́ ti gbà nyin kuro lọwọ́ gbogbo awọn ọta nyin, ati gbogbo wahala nyin; ẹnyin si ti wi fun u pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn awa nfẹ ki o fi ẹnikan jọba lori wa. Nisisiyi ẹ duro niwaju Oluwa nipa ẹyà nyin, ati nipa ẹgbẹgbẹrun nyin.

20 Samueli si mu ki gbogbo ẹya Israeli sunmọ tosi, a si mu ẹya Benjamini.

21 On si mu ki ẹya Benjamini sunmọ tosi nipa idile wọn, a mu idile Matri, a si mu Saulu ọmọ Kiṣi: nigbati nwọn si wá a kiri, nwọn kò si ri i.

22 Nitorina nwọn si tun bere lọdọ Oluwa sibẹ bi ọkunrin na yio wá ibẹ̀. Oluwa si dahùn wipe, Wõ, o pa ara rẹ̀ mọ lãrin ohun-elò.

23 Nwọn sare, nwọn si mu u lati ibẹ̀ wá: nigbati o si duro lãrin awọn enia na, o si ga jù gbogbo wọn lọ lati ejika rẹ̀ soke.

24 Samueli si wi fun gbogbo awọn enia na pe, Ẹnyin kò ri ẹniti Oluwa yàn fun ara rẹ̀, pe, ko si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo enia na? Gbogbo enia si ho ye, nwọn si wipe, Ki Ọba ki o pẹ!

25 Samueli si sọ ìwa ijọba fun awọn enia na. O si kọ ọ sinu iwe, o si fi i siwaju Oluwa. Samueli si rán gbogbo enia na lọ, olukuluku si ile rẹ̀.

26 Saulu pẹlu si lọ si ile rẹ̀ si Gibea; ẹgbẹ awọn alagbara ọkunrin si ba a lọ, ọkàn awọn ẹniti Ọlọrun tọ́.

27 Ṣugbọn awọn ọmọ Beliali wipe, Ọkunrin yi yio ti ṣe gbà wa? Nwọn kẹgàn rẹ̀, nwọn ko si mu ọrẹ wá fun u. On si dakẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31