10 Nwọn si kigbe pe Oluwa, nwọn si wipe, Awa ti dẹsẹ̀, nitoripe awa ti kọ̀ Oluwa silẹ, awa si ti nsin Baalimu ati Aṣtaroti: ṣugbọn nisisiyi, gba wa lọwọ́ awọn ọta wa, awa o si sìn ọ.
11 Oluwa si ran Jerubbaali, ati Bedani, ati Jefta ati Samueli, nwọn si gbà nyin lọwọ́ awọn ọta nyin niha gbogbo, ẹnyin si joko li alafia.
12 Nigbati ẹnyin si ri pe Nahaṣi ọba awọn ọmọ Ammoni tọ̀ nyin wá, ẹnyin wi fun mi pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ọba yio jẹ lori wa: nigbati Oluwa Ọlọrun nyin jẹ ọba nyin.
13 Njẹ nisisiyi wo ọba na ti ẹnyin yàn, ati ti ẹnyin fẹ, kiye si i, Oluwa fi ọba jẹ fun nyin.
14 Bi ẹnyin ba bẹ̀ru Oluwa, ti ẹnyin si sin i, ti ẹnyin si gbọ́ ohùn rẹ̀, ti ẹnyin ko si tapa si ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ati ọba nyin ti o jẹ lori nyin yio ma wà lẹhin Oluwa Ọlọrun nyin.
15 Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba gbà ohun Oluwa gbọ́, ti ẹ ba si tàpá si ọ̀rọ Oluwa, ọwọ́ Oluwa yio wà lara nyin si ibi, bi o ti wà lara baba nyin.
16 Nitorina nisisiyi ẹ duro ki ẹ si wo nkan nla yi, ti Oluwa yio ṣe li oju nyin.