18 Ẹgbẹ kan si gba ọ̀na Bet-horoni: ati ẹgbẹ kan si gbà ọ̀na agbegbe nì ti o kọju si afonifoji Seboimu ti o wà ni iha iju.
19 Kò si alagbẹdẹ ninu gbogbo ilẹ Israeli: nitori ti awọn Filistini wipe, Ki awọn Heberu ki o má ba rọ idà tabi ọ̀kọ.
20 Ṣugbọn gbogbo Israeli a ma tọ̀ awọn Filistini lọ, olukuluku lati pọ́n doje rẹ̀, ati ọ̀kọ rẹ̀, ati ãke rẹ̀, ati ọ̀ṣọ rẹ̀.
21 Ṣugbọn nwọn ni ayùn fun ọ̀ṣọ, ati fun ọ̀kọ, ati fun òya-irin ti ilẹ, ati fun ãke, ati lati pọn irin ọpa oluṣọ malu.
22 Bẹ̃li o si ṣe li ọjọ ijà, ti a kò ri idà, tabi ọ̀kọ lọwọ ẹnikẹni ninu awọn enia ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani; lọdọ Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ li a ri.
23 Awọn ọmọ-ogun Filistini jade lọ si ikọja Mikmaṣi.