24 Awọn ọkunrin Israeli si ri ipọnju gidigidi ni ijọ na: nitoriti Saulu fi awọn enia na bu pe, Ifibu ni fun ẹniti o jẹ onjẹ titi di alẹ titi emi o si fi gbẹsan lara awọn ọta mi. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu awọn enia na ti o fi ẹnu kan onjẹ.
25 Gbogbo awọn ara ilẹ na si de igbo kan, oyin sì wà lori ilẹ na.
26 Nigbati awọn enia si wọ inu igbo na, si kiye si i oyin na nkán; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o mu ọwọ́ rẹ̀ re ẹnu rẹ̀: nitoripe awọn enia bẹ̀ru ifibu na.
27 Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nigbati baba rẹ̀ fi ifibu kilọ fun awọn enia na: o si tẹ ori ọpa ti mbẹ lọwọ rẹ̀ bọ afara oyin na, o si fi i si ẹnu rẹ̀, oju rẹ̀ mejeji si walẹ.
28 Nigbana li ọkan ninu awọn enia na dahùn wipe, baba rẹ ti fi ifibu kilọ fun awọn enia na, pe, ifibu li ọkunrin na ti o jẹ onjẹ li oni. Arẹ̀ si mu awọn enia na.
29 Nigbana ni Jonatani wipe, baba mi yọ ilu li ẹnu, sa wo bi oju mi ti walẹ, nitori ti emi tọ diẹ wò ninu oyin yi.
30 A! nitotọ, ibaṣepe awọn enia na ti jẹ ninu ikogun awọn ọta wọn ti nwọn ri, pipa awọn Filistini iba ti pọ to?