11 Samueli si bi Jesse lere pe, gbogbo awọn ọmọ rẹ li o wà nihin bi? On si dahun wipe, abikẹhin wọn li o kù, sa wõ, o nṣọ agutan. Samueli si wi fun Jesse pe, Ranṣẹ ki o si mu u wá: nitoripe awa kì yio joko titi on o fi dé ihinyi.
12 O si ranṣẹ, o si mu u wá. On si jẹ ẹnipupa, ti o lẹwà loju, o si dara lati ma wò. Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si fi ororo sà a li àmi: nitoripe on na li eyi.
13 Nigbana ni Samueli mu iwo ororo, o si fi yà a si ọ̀tọ larin awọn arakunrin rẹ̀; Ẹmi Oluwa si bà le Dafidi lati ọjọ na lọ, Samueli si dide, o si lọ si Rama.
14 Ṣugbọn Ẹmi Oluwa fi Saulu silẹ, ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa si nyọ ọ li ẹnu.
15 Awọn iranṣẹ Saulu si wi fun u pe, Jọwọ, sa wõ ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun nyọ ọ li ẹnu.
16 Njẹ ki oluwa wa fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà niwaju rẹ̀ lati wá ọkunrin kan ti o mọ̀ ifi duru kọrin: yio si ṣe nigbati ẹmi buburu na lati ọdọ̀ Ọlọrun wá ba de si ọ, yio si fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara dùru, iwọ o si sàn.
17 Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ ba mi wá ọkunrin kan, ti o mọ̀ iṣẹ́ orin daju, ki ẹ si mu u tọ̀ mi wá.