17 Jesse si wi fun Dafidi ọmọ rẹ̀ pe, Jọwọ, mu agbado didin yi ti ẹfa kan, ati iṣu akara mẹwa yi fun awọn ẹgbọn rẹ, ki o si sure tọ awọn ẹgbọn rẹ ni ibudo;
18 Ki o si mu warakasi mẹwa wọnyi fun oloriogun ẹgbẹrun wọn, ki o si wo bi awọn ẹgbọn rẹ ti nṣe, ki o si gbà nkan àmi wọn wá.
19 Saulu, ati awọn, ati gbogbo ọkunrin Israeli si wà ni afonifoji Ela, nwọn mba awọn Filistini jà.
20 Dafidi si dide ni kutukutu owurọ, o si fi agutan wọnni le olutọju kan lọwọ, o si mura, o si lọ, gẹgẹ bi Jesse ti fi aṣẹ fun u; on si de ibi yàra, ogun na si nlọ si oju ijà, nwọn hó iho ogun.
21 Israeli ati Filistini si tẹgun, ogun si pade ogun.
22 Dafidi si fi nkan ti o nmu lọ le ọkan ninu awọn olutọju nkan gbogbo lọwọ, o si sare si ogun, o tọ awọn ẹgbọn rẹ̀ lọ, o si ki wọn.
23 Bi on si ti mba wọn sọ̀rọ, sa wõ, akikanju ọkunrin na, Filistini ti Gati, ti orukọ rẹ̀ njẹ Goliati si goke wá, lati ogun awọn Filistini, o si sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ ti o ti nsọ ri: Dafidi si gbọ́.