21 Israeli ati Filistini si tẹgun, ogun si pade ogun.
22 Dafidi si fi nkan ti o nmu lọ le ọkan ninu awọn olutọju nkan gbogbo lọwọ, o si sare si ogun, o tọ awọn ẹgbọn rẹ̀ lọ, o si ki wọn.
23 Bi on si ti mba wọn sọ̀rọ, sa wõ, akikanju ọkunrin na, Filistini ti Gati, ti orukọ rẹ̀ njẹ Goliati si goke wá, lati ogun awọn Filistini, o si sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ ti o ti nsọ ri: Dafidi si gbọ́.
24 Gbogbo ọkunrin Israeli, nigbati nwọn si ri ọkunrin na, nwọn si sa niwaju rẹ̀, ẹ̀ru si ba wọn gidigidi.
25 Awọn ọkunrin Israeli si wipe, Ẹnyin kò ri ọkunrin yi ti o goke wá ihin? lati pe Israeli ni ijà li o ṣe wá: yio si ṣe pe, ẹniti o ba pa ọkunrin na, ọba yio si fi ọrọ̀ pipọ fun u, yio si fun u li ọmọ rẹ̀ obinrin, yio si sọ ile baba rẹ di omnira ni Israeli.
26 Dafidi si wi fun awọn ọkunrin ti o duro li ọdọ rẹ̀ pe, Kili a o ṣe fun ọkunrin na ti o ba pa Filistini yi, ti o si mu ẹgàn na kuro li ara Israeli? tali alaikọla Filistini yi iṣe, ti yio fi ma gan ogun Ọlọrun alãye?
27 Awọn enia na si da a li ohùn gẹgẹ bi ọ̀rọ yi pe, Bayi ni nwọn o ṣe fun ọkunrin ti o ba pa a.