40 On si mu ọpa rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, o si ṣà okuta marun ti o jọlọ̀ ninu odò, o si fi wọn sinu apò oluṣọ agutan ti o ni, ani sinu asùwọn: kànakana rẹ̀ si wà li ọwọ́ rẹ̀; o si sunmọ Filistini na.
41 Filistini na si mbọ̀, o si nsunmọ Dafidi; ati ọkunrin ti o rù awà rẹ̀ si mbọ̀ niwaju rẹ̀.
42 Nigbati Filistini na si wò, ti o si ri Dafidi, o ṣata rẹ̀: nitoripe ọdọmọdekunrin ni iṣe, o pọn, o si ṣe arẹwa enia.
43 Filistini na si wi fun Dafidi pe, Emi ha nṣe aja bi, ti iwọ fi mu ọpá tọ̀ mi wá? Filistini na si fi Dafidi re nipa awọn ọlọrun rẹ̀.
44 Filistini na si wi fun Dafidi pe, Mã bọ̀; emi o si fi ẹran ara rẹ fun awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati fun awọn ẹranko papa.
45 Dafidi si wi fun Filistini na pe, Iwọ mu idà, ati ọ̀kọ, ati awà tọ̀ mi wá; ṣugbọn emi tọ̀ ọ wá li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun ogun Israeli ti iwọ ti gàn.
46 Loni yi li Oluwa yio fi iwọ le mi lọwọ́, emi o pa ọ, emi o si ke ori rẹ kuro li ara rẹ; emi o si fi okú ogun Filistini fun ẹiyẹ oju ọrun loni yi, ati fun ẹranko igbẹ; gbogbo aiye yio si mọ̀ pe, Ọlọrun wà fun Israeli.