14 Dafidi si ṣe ọlọgbọ́n ni gbogbo iṣe rẹ̀; Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.
15 Nigbati Saulu ri pe, o nhuwa ọgbọ́n gidigidi, o si mbẹ̀ru rẹ̀.
16 Gbogbo Israeli ati Juda si fẹ Dafidi, nitoripe a ma lọ a si ma bọ̀ niwaju wọn.
17 Saulu si wi fun Dafidi pe, Wo Merabu ọmọbinrin mi, eyi agbà, on li emi o fi fun ọ li aya: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alagbara fun mi, ki o si ma ja ija Oluwa. Nitoriti Saulu ti wi bayi pe, Màṣe jẹ ki ọwọ́ mi ki o wà li ara rẹ̀; ṣugbọn jẹ ki ọwọ́ awọn Filistini ki o wà li ara rẹ̀.
18 Dafidi si wi fun Saulu pe, Tali emi, ati ki li ẹmi mi, tabi idile baba mi ni Israeli, ti emi o fi wa di ana ọba.
19 O si ṣe, li akoko ti a ba fi Merabu ọmọbinrin Saulu fun Dafidi, li a si fi i fun Adrieli ara Meholati li aya.
20 Mikali ọmọbinrin Saulu si fẹran Dafidi, nwọn si wi fun Saulu: nkan na si tọ li oju rẹ̀.