2 Saulu si mu u sọdọ lọjọ na, ko si jẹ ki o lọ sọdọ baba rẹ̀ mọ.
3 Jonatani on Dafidi si ba ara wọn mulẹ; nitoripe o fẹ ẹ gẹgẹ bi o ti fẹ ọkàn ara rẹ̀.
4 Jonatani si bọ aṣọ ileke ti o wà li ara rẹ̀ o si fi i fun Dafidi, ati ihamọra rẹ̀, titi de idà rẹ̀, ọrun rẹ̀, ati amure rẹ̀.
5 Dafidi a si ma lọ si ibikibi ti Saulu rán a, a ma huwa ọlọgbọ́n: Saulu si fi i jẹ olori ogun, o si dara loju gbogbo awọn enia, ati pẹlupẹlu loju awọn iranṣẹ Saulu.
6 O si ṣe, bi nwọn ti de, nigbati Dafidi ti ibi ti o gbe pa Filistini na bọ̀, awọn obinrin si ti gbogbo ilu Israeli jade wá, nwọn nkọrin nwọn si njo lati wá ipade Saulu ọba, ti awọn ti ilù, ati ayọ̀, ati duru.
7 Awọn obinrin si ndá, nwọn si ngbe orin bi nwọn ti nṣire, nwọn si nwipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbarun tirẹ̀.
8 Saulu si binu gidigidi, ọ̀rọ na si buru loju rẹ̀ o si wipe, Nwọn fi ẹgbẹgbarun fun Dafidi, nwọn si fi ẹgbẹgbẹrun fun mi, kili o si kù fun u bikoṣe ijọba.