9 Saulu si nfi oju ilara wo Dafidi lati ọjọ na lọ.
10 O si ṣe ni ijọ keji, ti ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun wá si ba le Saulu, on si sọtẹlẹ li arin ile; Dafidi si fi ọwọ́ rẹ̀ ṣire lara duru bi igba atẹhinwa; ẹṣín kan mbẹ lọwọ Saulu.
11 Saulu si sọ ẹṣín ti o wà lọwọ rẹ̀ na; o si wipe, Emi o pa Dafidi li apa mọ́ ogiri. Dafidi si yẹra kuro niwaju rẹ lẹ̃meji.
12 Saulu si bẹ̀ru Dafidi, nitoripe Oluwa wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa kọ̀ Saulu.
13 Nitorina Saulu si mu u kuro lọdọ rẹ̀, o si fi i jẹ olori ogun ẹgbẹrun kan, o si nlọ, o si mbọ̀ niwaju awọn enia na.
14 Dafidi si ṣe ọlọgbọ́n ni gbogbo iṣe rẹ̀; Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.
15 Nigbati Saulu ri pe, o nhuwa ọgbọ́n gidigidi, o si mbẹ̀ru rẹ̀.