6 Oluwa pa, o si sọ di ayè: o mu sọkalẹ lọ si ibojì, o si gbe soke.
7 Oluwa sọ di talaka, o si sọ di ọlọrọ̀: o rẹ̀ silẹ, o si gbe soke.
8 O gbe talaka soke lati inu erupẹ wá, o gbe alagbe soke lati ori ãtan wá, lati ko wọn jọ pẹlu awọn ọmọ-alade, lati mu wọn jogun itẹ ogo: nitori pe ọwọ̀n aiye ti Oluwa ni, o si ti gbe aiye ka ori wọn.
9 Yio pa ẹṣẹ awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ, awọn enia buburu ni yio dakẹ li okunkun; nipa agbara kò si ọkunrin ti yio bori.
10 Ao fọ́ awọn ọta Oluwa tutu; lati ọrun wá ni yio san ãrá si wọn: Oluwa yio ṣe idajọ opin aiye; yio fi agbara fun ọba rẹ̀, yio si gbe iwo ẹni-amì-ororo rẹ̀ soke.
11 Elkana si lọ si Rama si ile rẹ̀. Ọmọ na si nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli alufa.
12 Awọn ọmọ Eli si jẹ ọmọ Beliali; nwọn kò mọ̀ Oluwa.