20 Emi o si ta ọfà mẹta si ìha ibẹ̀ na, gẹgẹ bi ẹnipe mo ta si àmi kan.
21 Si wõ, emi o ran ọmọde-kọnrin kan pe, Lọ, ki o si wá ọfa wọnni. Bi emi ba tẹnu mọ ọ fun ọmọkunrin na, pe, Wõ, ọfa wọnni wà lẹhin rẹ, ṣà wọn wá; nigbana ni iwọ o ma bọ̀; nitoriti alafia mbẹ fun ọ, kò si ewu; bi Oluwa ti wà.
22 Ṣugbọn bi emi ba wi bayi fun ọmọde-kọnrin na pe, Wõ ọfa na mbẹ niwaju rẹ; njẹ ma ba tirẹ lọ; Oluwa li o rán ọ lọ.
23 Niti ọ̀rọ ti emi ati iwọ si ti jumọ sọ, wõ, ki Oluwa ki o wà larin iwọ ati emi titi lailai.
24 Bẹ̃ni Dafidi sì pa ara rẹ̀ mọ li oko; nigbati oṣu titun si de, ọba si joko lati jẹun.
25 Ọba si joko ni ipò rẹ̀ bi igba atijọ lori ijoko ti o gbe ogiri; Jonatani si dide, Abneri si joko ti Saulu, ipò Dafidi si ṣofo.
26 Ṣugbọn Saulu kò sọ nkan nijọ na; nitoriti on rò pe, Nkan ṣe e ni, on ṣe alaimọ́ ni; nitotọ o ṣe alaimọ́ ni.