10 On si bere lọdọ̀ Oluwa fun u, o si fun u li onjẹ o si fun u ni idà Goliati ara Filistia.
11 Ọba si ranṣẹ pe Ahimeleki alufa, ọmọ Ahitubu ati gbogbo idile baba rẹ̀, awọn alufa ti o wà ni Nobu: gbogbo wọn li o si wá sọdọ ọba.
12 Saulu si wipe, Njẹ gbọ́, iwọ ọmọ Ahitubu. On si wipe, Emi nĩ, oluwa mi.
13 Saulu si wi fun u pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi dimọlù si mi, iwọ ati ọmọ Jesse, ti iwọ fi fun u li akara, ati idà, ati ti iwọ fi bere fun u lọdọ Ọlọrun, ki on ki o le dide si mi, lati ba dè mi, bi o ti ri loni?
14 Ahimeleki si da ọba lohun, o si wipe, Tali oluwa rẹ̀ ti o ṣe enia re ninu gbogbo awọn iranṣẹ rẹ bi Dafidi, ẹniti iṣe ana ọba, ẹniti o ngbọ́ tirẹ, ti o si li ọla ni ile rẹ?
15 Oni li emi o ṣẹṣẹ ma bere li ọwọ́ Ọlọrun fun u bi? ki eyini jinà si mi: ki ọba ki o máṣe ka nkankan si iranṣẹ rẹ̀ lọrùn, tabi si gbogbo idile baba mi: nitoripe iranṣẹ rẹ kò mọ̀ kan ninu gbogbo nkan yi, diẹ tabi pupọ.
16 Ọba si wipe, Ahimeleki, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo idile baba rẹ.