1. Sam 22:13-19 YCE

13 Saulu si wi fun u pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi dimọlù si mi, iwọ ati ọmọ Jesse, ti iwọ fi fun u li akara, ati idà, ati ti iwọ fi bere fun u lọdọ Ọlọrun, ki on ki o le dide si mi, lati ba dè mi, bi o ti ri loni?

14 Ahimeleki si da ọba lohun, o si wipe, Tali oluwa rẹ̀ ti o ṣe enia re ninu gbogbo awọn iranṣẹ rẹ bi Dafidi, ẹniti iṣe ana ọba, ẹniti o ngbọ́ tirẹ, ti o si li ọla ni ile rẹ?

15 Oni li emi o ṣẹṣẹ ma bere li ọwọ́ Ọlọrun fun u bi? ki eyini jinà si mi: ki ọba ki o máṣe ka nkankan si iranṣẹ rẹ̀ lọrùn, tabi si gbogbo idile baba mi: nitoripe iranṣẹ rẹ kò mọ̀ kan ninu gbogbo nkan yi, diẹ tabi pupọ.

16 Ọba si wipe, Ahimeleki, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo idile baba rẹ.

17 Ọba si wi fun awọn aṣaju ti ima sare niwaju ọba, ti o duro tì i, pe, Yipada ki ẹ si pa awọn alufa Oluwa; nitoripe ọwọ́ wọn wà pẹlu Dafidi, ati nitoripe, nwọn mọ̀ igbati on sa, nwọn kò si sọ ọ li eti mi. Ṣugbọn awọn iranṣẹ ọba ko si jẹ fi ọwọ́ wọn le awọn alufa Oluwa lati pa wọn.

18 Ọba si wi fun Doegi pe, Iwọ, yipada, ki o si pa awọn alufa. Doegi ara Edomu si yipada, o si kọlu awọn alufa, o si pa li ọjọ na, àrunlelọgọrin enia ti nwọ aṣọ ọgbọ̀ Efodu.

19 O si fi oju ida pa ara Nobu, ilu awọn alufa na ati ọkunrin ati obinrin, ọmọ wẹrẹ, ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agutan.