18 Ọba si wi fun Doegi pe, Iwọ, yipada, ki o si pa awọn alufa. Doegi ara Edomu si yipada, o si kọlu awọn alufa, o si pa li ọjọ na, àrunlelọgọrin enia ti nwọ aṣọ ọgbọ̀ Efodu.
19 O si fi oju ida pa ara Nobu, ilu awọn alufa na ati ọkunrin ati obinrin, ọmọ wẹrẹ, ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agutan.
20 Ọkan ninu awọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu ti a npè ni Abiatari si bọ́; o si sa asala tọ Dafidi lọ.
21 Abiatari si fi han Dafidi pe, Saulu pa awọn alufa Oluwa tan.
22 Dafidi si wi fun Abiatari pe, emi ti mọ̀ ni ijọ na, nigbati Doegi ara Edomu nì ti wà nibẹ̀ pe, nitotọ yio sọ fun Saulu: nitori mi li a ṣe pa gbogbo idile baba rẹ.
23 Iwọ joko nihin lọdọ mi, máṣe bẹ̀ru, nitoripe ẹniti nwá ẹmi mi, o nwá ẹmi rẹ: ṣugbọn lọdọ mi ni iwọ o wà li ailewu.