25 Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ iwá a. Nwọn si sọ fun Dafidi: o si sọkalẹ wá si ibi okuta kan, o si joko li aginju ti Maoni. Saulu si gbọ́, o si lepa Dafidi li aginju Maoni.
26 Saulu si nrin li apakan oke kan, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ li apa keji oke na: Dafidi si yara lati sa kuro niwaju Saulu; nitoripe Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti rọ̀gba yi Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ka lati mu wọn.
27 Ṣugbọn onṣẹ kan si tọ Saulu wá, o si wipe, iwọ yara ki o si wá, nitoriti awọn Filistini ti gbe ogun tì ilẹ wa.
28 Saulu si pada kuro ni lilepa Dafidi, o si lọ ipade awọn Filistini: nitorina ni nwọn si se npe ibẹ̀ na ni Selahammalekoti. (ni itumọ rẹ̀, okuta ipinyà.)
29 Dafidi ti goke lati ibẹ lọ, o si joko nibi ti o sapamọ si ni Engedi.