7 A si sọ fun Saulu pe, Dafidi wa si Keila. Saulu si wipe, Ọlọrun ti fi i le mi lọwọ; nitoripe a ti dí i mọ tan, nitori o wọ inu ilu ti o ni ilẹkun ati ikere.
8 Saulu si pe gbogbo awọn enia na jọ si ogun, lati sọkalẹ lọ si Keila, lati ká Dafidi mọ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀.
9 Dafidi si mọ̀ pe Saulu ti gbèro buburu si on; o si wi fun Abiatari alufa na pe, Mu efodu na wá nihinyi.
10 Dafidi si wipe Oluwa Ọlọrun Israeli, lõtọ ni iranṣẹ rẹ ti gbọ́ pe Saulu nwá ọ̀na lati wá si Keila, lati wá fọ ilu na nitori mi.
11 Awọn agba ilu Keila yio fi mi le e lọwọ bi? Saulu yio ha sọkalẹ, gẹgẹ bi iranṣẹ rẹ ti gbọ́ bi? Oluwa Ọlọrun Israeli, emi bẹ̀ ọ, wi fun iranṣẹ rẹ. Oluwa si wipe, Yio sọkalẹ wá.
12 Dafidi si wipe, Awọn agbà ilu Keila yio fi emi ati awọn ọmọkunrin mi le Saulu lọwọ bi? Oluwa si wipe, Nwọn o fi ọ le wọn lọwọ.
13 Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn to ẹgbẹta enia si dide, nwọn lọ kuro ni Keila, nwọn si lọ si ibikibi ti nwọn le lọ. A si wi fun Saulu pe, Dafidi ti sa kuro ni Keila; ko si lọ si Keila mọ.