13 Gẹgẹ bi owe igba atijọ ti wi, Ìwabuburu a ma ti ọdọ awọn enia buburu jade wá; ṣugbọn ọwọ́ mi kì yio si lara rẹ.
14 Nitori tani ọba Israeli fi jade? tani iwọ nlepa? okú aja, tabi eṣinṣin?
15 Ki Oluwa ki o ṣe onidajọ, ki o si dajọ larin emi ati iwọ, ki o si wò ki o gbejà mi, ki o si gbà mi kuro li ọwọ́ rẹ.
16 O si ṣe, nigbati Dafidi si dakẹ ọ̀rọ wọnyi isọ fun Saulu, Saulu si wipe, Ohùn rẹ li eyi bi, Dafidi ọmọ mi? Saulu si gbe ohùn rẹ̀ soke, o sọkun.
17 O si wi fun Dafidi pe, Iwọ ṣe olododo jù mi lọ: nitoripe iwọ ti fi ire san fun mi, emi fi ibi san fun ọ.
18 Iwọ si fi ore ti iwọ ti ṣe fun mi hàn loni: nigbati o jẹ pe, Oluwa ti fi emi le ọ li ọwọ́, iwọ kò si pa mi.
19 Nitoripe bi enia ba ri ọta rẹ̀, o le jẹ ki o lọ li alafia bi? Oluwa yio si fi ire san eyi ti iwọ ṣe fun mi loni.