22 Bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ ni ki Ọlọrun ki o ṣe si awọn ọta Dafidi, bi emi ba fi ẹnikẹni ti ntọ̀ sara ogiri silẹ ninu gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀ titi di imọlẹ owurọ.
23 Abigaili si ri Dafidi, on si yara, o sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ, o si dojubolẹ niwaju Dafidi, o si tẹ ara rẹ̀ ba silẹ.
24 O si wolẹ li ẹba ẹsẹ rẹ̀ o wipe, Oluwa mi, fi ẹ̀ṣẹ yi ya mi: ki o si jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ, emi bẹ̀ ọ, sọ̀rọ leti rẹ, ki o si gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹbinrin rẹ.
25 Oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, má ka ọkunrin Beliali yi si, ani Nabali: nitoripe bi orukọ rẹ̀ ti jẹ bẹ̃li on na ri: Nabali li orukọ rẹ̀, aimoye si wà pẹlu rẹ̀; ṣugbọn emi iranṣẹbinrin rẹ kò ri awọn ọmọkunrin oluwa mi, ti iwọ rán.
26 Njẹ, oluwa mi, bi Oluwa ti wà lãye, ati bi ẹmi rẹ si ti wà làye, bi Oluwa si ti da ọ duro lati wá ta ẹjẹ silẹ, ati lati fi ọwọ́ ara rẹ gbẹsan; njẹ, ki awọn ọta rẹ, ati awọn ẹniti ngbero ibi si oluwa mi ri bi Nabali.
27 Njẹ eyi ni ẹbùn ti iranṣẹbinrin rẹ mu wá fun oluwa mi, jẹ ki a si fi fun awọn ọmọkunrin ti ntọ oluwa mi lẹhin.
28 Emi bẹ̀ ọ, fi irekọja iranṣẹbinrin rẹ ji i: nitori ti Oluwa yio sa ṣe ile ododo fun oluwa mi, nitori ogun Oluwa ni oluwa mi njà; a kò si ri ibi lọwọ rẹ ni gbogbo ọjọ rẹ.