41 O si dide, o si dojubolẹ, o si wipe, Wõ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o jẹ iranṣẹ kan lati ma wẹ ẹsẹ awọn iranṣẹ oluwa mi.
42 Abigaili si yara, o dide, o si gun kẹtẹkẹtẹ, awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ marun si tẹle e lẹhin; on si tẹle awọn iranṣẹ Dafidi, o si wa di aya rẹ̀.
43 Dafidi si mu Ahinoamu ti Jesreeli; awọn mejeji si jẹ aya rẹ̀.
44 Ṣugbọn Saulu ti fi Mikali ọmọ rẹ̀ obinrin, aya Dafidi, fun Falti ọmọ Laisi ti iṣe ara Gallimu.