1 AWỌN ara Sifi si tọ̀ Saulu wá si Gibea, nwọn wipe, Ṣe Dafidi fi ara rẹ̀ pamọ nibi oke Hakila, eyi ti o wà niwaju Jeṣimoni?
2 Saulu si dide o si sọkalẹ lọ si ijù Sifi, ẹgbẹ̀dogun àṣayàn enia ni Israeli si pẹlu rẹ̀ lati wá Dafidi ni iju Sifi.
3 Saulu si pagọ rẹ̀ ni ibi oke Hakila ti o wà niwaju Jeṣimoni li oju ọ̀na. Dafidi si joko ni ibi iju na, o si ri pe Saulu ntẹle on ni iju na.
4 Dafidi si ran amí jade, o si mọ̀ nitõtọ pe Saulu mbọ̀.
5 Dafidi si dide, o si wá si ibi ti Saulu pagọ si: Dafidi si ri ibi ti Saulu gbe dubulẹ si, ati Abneri ọmọ Neri, olori ogun rẹ̀: Saulu si dubulẹ larin awọn kẹ̀kẹ́, awọn enia na si pagọ wọn yi i ka.