11 Oluwa má jẹ ki emi nà ọwọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa: njẹ, emi bẹ ọ, mu ọ̀kọ na ti mbẹ nibi timtim rẹ̀, ati igo omi ki a si ma lọ.
12 Dafidi si mu ọ̀kọ na, ati igo omi na kuro nibi timtim Saulu: nwọn si ba ti wọn lọ, kò si si ẹnikan ti o ri i, tabi ti o mọ̀; kò si si ẹnikan ti o ji; gbogbo wọn si sùn; nitoripe orun àjika lati ọdọ Oluwa wá ti ṣubu lù wọn.
13 Dafidi si rekọja si iha keji, o si duro lori oke kan ti o jina rere; afo nla kan si wà lagbedemeji wọn:
14 Dafidi si kọ si awọn enia na, ati si Abneri ọmọ Neri wipe, Iwọ kò dahun, Abneri? Nigbana ni Abneri si dahun wipe, Iwọ tani npe ọba?
15 Dafidi si wi fun Abneri pe, Alagbara ọkunrin ki iwọ nṣe ndan? tali o si dabi iwọ ni Israeli? njẹ ẽṣe ti iwọ ko tọju ọba oluwa rẹ? nitori ẹnikan ninu awọn enia na ti wọle wá lati pa ọba oluwa rẹ.
16 Nkan ti iwọ ṣe yi kò dara. Bi Oluwa ti mbẹ, o tọ ki ẹnyin ki o kú, nitoripe ẹnyin ko pa oluwa nyin mọ, ẹni-àmi-ororo Oluwa. Njẹ si wo ibiti ọ̀kọ ọba gbe wà, ati igò omi ti o ti wà nibi timtim rẹ̀.
17 Saulu si mọ̀ ohùn Dafidi, o si wipe, Ohùn rẹ li eyi bi, Dafidi ọmọ mi? Dafidi si wipe, Ohùn mi ni, oluwa mi, ọba.