18 On si wipe, Nitori kini oluwa mi ṣe nlepa iranṣẹ rẹ? kili emi ṣe? tabi ìwa buburu wo li o wà li ọwọ́ mi.
19 Njẹ emi bẹ ọ ọba, oluwa mi, gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹ rẹ. Bi Oluwa ba ti ru iwọ soke si mi, jẹ ki on ki o gbà ẹbọ; ṣugbọn bi o ba si ṣepe ọmọ enia ni, ifibu ni ki nwọn ki o jasi niwaju Oluwa; nitori nwọn le mi jade loni ki emi má gbe inu ilẹ ini Oluwa, wipe, Lọ, sin awọn ọlọrun miran.
20 Njẹ máṣe jẹ ki ẹjẹ mi ki o ṣàn silẹ niwaju Oluwa: nitori ọba Israeli jade lati wá itapin bi ẹni ndọdẹ aparo lori oke-nla.
21 Saulu si wipe, Emi ti dẹṣẹ: yipada, Dafidi ọmọ mi: nitoripe emi kì yio wá ibi rẹ mọ, nitoriti ẹmi mi sa ti ṣe iyebiye li oju rẹ loni: wõ, emi ti nhuwa wère mo si ti ṣina jọjọ.
22 Dafidi si dahun, o si wipe, Wo ọ̀kọ̀ ọba! ki o si jẹ ki ọkan ninu awọn ọmọkunrin rekọja wá gbà a.
23 Ki Oluwa ki o san a fun olukuluku ododo rẹ̀ ati otitọ rẹ̀: nitoripe Oluwa ti fi ọ le mi lọwọ loni, ṣugbọn emi ko fẹ nawọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa.
24 Si wõ, gẹgẹ bi ẹmi rẹ ti tobi loni loju mi, bẹni ki ẹmi mi ki o tobi loju Oluwa, ki o si gbà mi lọwọ ibi gbogbo.