21 Saulu si wipe, Emi ti dẹṣẹ: yipada, Dafidi ọmọ mi: nitoripe emi kì yio wá ibi rẹ mọ, nitoriti ẹmi mi sa ti ṣe iyebiye li oju rẹ loni: wõ, emi ti nhuwa wère mo si ti ṣina jọjọ.
22 Dafidi si dahun, o si wipe, Wo ọ̀kọ̀ ọba! ki o si jẹ ki ọkan ninu awọn ọmọkunrin rekọja wá gbà a.
23 Ki Oluwa ki o san a fun olukuluku ododo rẹ̀ ati otitọ rẹ̀: nitoripe Oluwa ti fi ọ le mi lọwọ loni, ṣugbọn emi ko fẹ nawọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa.
24 Si wõ, gẹgẹ bi ẹmi rẹ ti tobi loni loju mi, bẹni ki ẹmi mi ki o tobi loju Oluwa, ki o si gbà mi lọwọ ibi gbogbo.
25 Saulu si wi fun Dafidi pe, Alabukunfun ni iwọ, Dafidi ọmọ mi: nitõtọ iwọ o si ṣe nkan nla, nitotọ iwọ o si bori. Dafidi si ba ọ̀na rẹ̀ lọ, Saulu si yipada si ibugbe rẹ̀.